1 Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ dẹtí sí ẹ̀kọ́ mi;ẹ tẹ́tí si ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
2 N óo la ẹnu mi tòwe-tòwe;n óo fa ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àtijọ́ yọ,
3 ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,ohun tí àwọn baba ńlá wa ti sọ fún wa.
4 A kò ní fi pamọ́ fún àwọn ọmọ wọn;a óo máa sọ ọ́ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn–iṣẹ́ ńlá OLUWA ati ìṣe akọni rẹ̀,ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe.
5 Ó fi ìlànà lélẹ̀ fún ìdílé Jakọbu;ó gbé òfin kalẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.Ó pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá wa,pé kí wọ́n fi kọ́ àwọn ọmọ wọn.
6 Kí àwọn ìran tí ń bọ̀ lè mọ̀ ọ́n,àní, àwọn ọmọ tí a kò tíì bí,kí àwọn náà ní ìgbà tiwọnlè sọ ọ́ fún àwọn ọmọ wọn.
7 Kí wọn lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun,kí wọn má gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,kí wọn sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́,
8 kí wọn má dàbí àwọn baba ńlá wọn,ìran àwọn olóríkunkun ati ọlọ̀tẹ̀,àwọn tí ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin,tí ẹ̀mí wọn kò sì dúró gbọningbọnin ti Olodumare.
9 Àwọn ọmọ Efuraimu kó ọrun, wọ́n kó ọfà,ṣugbọn wọ́n pẹ̀yìndà lọ́jọ́ ìjà.
10 Wọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́,wọ́n kọ̀, wọn kò jẹ́ pa òfin rẹ̀ mọ́.
11 Wọ́n gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe hàn wọ́n.
12 Ní ìṣojú àwọn baba ńlá wọn, ó ṣe ohun ìyanu,ní ilẹ̀ Ijipti, ní oko Soani.
13 Ó pín òkun níyà, ó jẹ́ kí wọ́n kọjá láàrin rẹ̀;ó sì mú kí omi nàró bí òpó ńlá.
14 Ó fi ìkùukùu ṣe atọ́nà wọn ní ọ̀sán,ó fi ìmọ́lẹ̀ iná tọ́ wọn sọ́nà ní gbogbo òru.
15 Ó la àpáta ni aṣálẹ̀,ó sì fún wọn ní omi mu lọpọlọpọ bí ẹni pé láti inú ibú.
16 Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta;ó sì mú kí ó ṣàn bí odò.
17 Sibẹsibẹ wọn ò dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá;wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo ninu aṣálẹ̀.
18 Wọ́n dán Ọlọrun wò ninu ọkàn wọn,wọ́n ń wá oúnjẹ tí yóo tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn.
19 Wọ́n sọ̀rọ̀ ìwọ̀sí sí Ọlọrun, wọ́n ní,“Ṣé Ọlọrun lè gbé oúnjẹ kalẹ̀ fún wa ninu aṣálẹ̀?
20 Lóòótọ́ ó lu òkúta tí omi fi tú jáde,tí odò sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn.Ṣé ó lè fún wa ní òkèlè pẹlu,àbí ó lè pèsè ẹran fún àwọn eniyan rẹ̀?”
21 Nítorí náà nígbà tí OLUWA gbọ́,inú bí i;iná mọ́ ìdílé Jakọbu,inú OLUWA sì ru sí àwọn ọmọ Israẹli;
22 nítorí pé wọn kò gba Ọlọrun gbọ́;wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé agbára ìgbàlà rẹ̀.
23 Sibẹ ó pàṣẹ fún ìkùukùu lókè,ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀.
24 Ó rọ òjò mana sílẹ̀fún wọn láti jẹ,ó sì fún wọn ní ọkà ọ̀run.
25 Ọmọ eniyan jẹ lára oúnjẹ àwọn angẹli;Ọlọrun fún wọn ní oúnjẹ àjẹtẹ́rùn.
26 Ó mú kí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn fẹ́ ní ojú ọ̀run,ó sì fi agbára rẹ̀ darí afẹ́fẹ́ ìhà gúsù;
27 ó sì rọ̀jò ẹran sílẹ̀ fún wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀;àní, ẹyẹ abìyẹ́ bíi yanrìn etí òkun.
28 Ó mú kí wọn bọ́ sílẹ̀ láàrin ibùdó;yíká gbogbo àgọ́ wọn,
29 Àwọn eniyan náà jẹ, wọ́n sì yó;nítorí pé Ọlọrun fún wọn ní ohun tí ọkàn wọn fẹ́.
30 Ṣugbọn kí wọn tó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn,àní, nígbà tí wọn ṣì ń jẹun lọ́wọ́.
31 Ọlọrun bínú sí wọn;ó pa àwọn tí ó lágbára jùlọ ninu wọn,ó sì lu àṣàyàn àwọn ọdọmọkunrin Israẹli pa.
32 Sibẹsibẹ wọ́n tún dẹ́ṣẹ̀;pẹlu gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọn kò gbàgbọ́.
33 Nítorí náà ó mú kí ọjọ́ ayé wọn pòórá bí afẹ́fẹ́;wọ́n sì lo ọjọ́ ayé wọn pẹlu ìjayà.
34 Nígbàkúùgbà tí ó bá ń pa wọ́n, wọn á wá a;wọn á ronupiwada, wọn á sì wá Ọlọrun tọkàntọkàn.
35 Wọn á ranti pé Ọlọrun ni àpáta ààbò wọn,ati pé Ọ̀gá Ògo ni olùràpadà wọn.
36 Ṣugbọn wọn kàn ń fi ẹnu wọn pọ́n ọn ni;irọ́ ni wọ́n sì ń pa fún un.
37 Ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin lọ́dọ̀ rẹ̀;wọn kò sì pa majẹmu rẹ̀ mọ́.
38 Sibẹ, nítorí pé aláàánú ni, ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n,kò sì pa wọ́n run;ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró,tí kò sì fi gbogbo ara bínú sí wọn.
39 Ó ranti pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,afẹ́fẹ́ lásán tí ń fẹ́ kọjá lọ, tí kò sì ní pada mọ́.
40 Ìgbà mélòó ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ninu ijù,tí wọ́n sì bà á lọ́kàn jẹ́ ninu aṣálẹ̀!
41 Wọ́n dán an wò léraléra,wọ́n sì mú Ẹni Mímọ́ Israẹli bínú.
42 Wọn kò ranti agbára rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ranti ọjọ́ tí ó rà wọ́n pada lọ́wọ́ ọ̀tá;
43 nígbà tí ó ṣe iṣẹ́ abàmì ní ilẹ̀ Ijipti,tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní oko Soani.
44 Ó sọ omi odò wọn di ẹ̀jẹ̀,tí wọn kò fi lè mu omi wọn.
45 Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin sí wọn tí ó jẹ wọ́n,ati ọ̀pọ̀lọ́ tí ó pa wọ́n run.
46 Ó mú kí kòkòrò jẹ èso ilẹ̀ wọn;eṣú sì jẹ ohun ọ̀gbìn wọn.
47 Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́;ó sì fi òjò dídì run igi Sikamore wọn.
48 Ó fi yìnyín pa mààlúù wọn;ó sì sán ààrá pa agbo aguntan wọn.
49 Ó tú ibinu gbígbóná rẹ̀ lé wọn lórí:ìrúnú, ìkannú, ati ìpọ́njú,wọ́n dàbí ikọ̀ ìparun.
50 Ó fi àyè gba ibinu rẹ̀;kò dá ẹ̀mí wọn sí,ó sì fi àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n.
51 O kọlu gbogbo àkọ́bí wọn ní ilẹ̀ Ijipti,àní, gbogbo àrẹ̀mọ ninu àgọ́ àwọn ọmọ Hamu.
52 Lẹ́yìn náà, ó kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde bí agbo ẹranó sì dà wọ́n láàrin aṣálẹ̀ bí agbo aguntan.
53 Ó dà wọ́n lọ láìléwu, ẹ̀rù kò bà wọ́n;òkun sì bo àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀.
54 Ó kó wọn wá sí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀,sí orí òkè tí ó ti fi agbára rẹ̀ gbà.
55 Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde kí wọn ó tó dé ibẹ̀;ó pín ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn bí ohun ìní;ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli jókòó ninu àgọ́ wọn.
56 Sibẹ, wọ́n dán Ọ̀gá Ògo wò, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí i;wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ̀.
57 Wọ́n yipada, wọ́n sì hu ìwà ọ̀dàlẹ̀bíi ti àwọn baba ńlá wọn;wọn kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, wọ́n dàbí ọfà tí ó tẹ̀.
58 Wọ́n fi ojúbọ àwọn oriṣa wọn bí i ninu;wọ́n sì fi ère wọn mú un jowú.
59 Nígbà tí Ọlọrun gbọ́, inú bí i gidigidi;ó sì kọ Israẹli sílẹ̀ patapata.
60 Ó kọ ibùgbé rẹ̀ ní Ṣilo sílẹ̀,àní, àgọ́ rẹ̀ láàrin ọmọ eniyan.
61 Ó jẹ́ kí á gbé àmì agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn;ó sì fi ògo rẹ̀ lé ọ̀tá lọ́wọ́.
62 Ó jẹ́ kí á fi idà pa àwọn eniyan rẹ̀;ó sì bínú gidigidi sí àwọn eniyan ìní rẹ̀.
63 Iná run àwọn ọdọmọkunrin wọn;àwọn ọdọmọbinrin wọn kò sì rójú kọrin igbeyawo.
64 Àwọn alufaa kú ikú ogun;àwọn opó wọn kò sì rójú sọkún.
65 Lẹ́yìn náà, OLUWA dìde bí ẹni tají lójú oorun,bí ọkunrin alágbára tí ó mu ọtí yó tí ó ń kígbe.
66 Ó lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ sẹ́yìn;ó dójú tì wọ́n títí ayé.
67 Ó kọ àgọ́ àwọn ọmọ Josẹfu sílẹ̀;kò sì yan ẹ̀yà Efuraimu;
68 ṣugbọn ó yan ẹ̀yà Juda,ó sì yan òkè Sioni tí ó fẹ́ràn.
69 Níbẹ̀ ni ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀ tí ó ga bí ọ̀run sí,ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí ayé títí lae.
70 Ó yan Dafidi iranṣẹ rẹ̀;ó sì mú un láti inú agbo ẹran.
71 Ó mú un níbi tí ó ti ń tọ́jú àwọn aguntantí ó lọ́mọ lẹ́yìn,kí ó lè máa tọ́jú àwọn ọmọ Jakọbu, eniyan rẹ̀,àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan ìní rẹ̀.
72 Ó tọ́jú wọn pẹlu òdodo,ó sì tọ́ wọn pẹlu ìmọ̀.