1 OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi;dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá;
2 àwọn tí ó ń pète ibi lọ́kàn wọn,tí wọ́n sì ń dá ogun sílẹ̀ nígbàkúùgbà,
3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn, ó mú bí ahọ́n ejò;oró paramọ́lẹ̀ sì ń bẹ ninu eyín wọn.
4 OLUWA, ṣọ́ mi lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú;dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá,tí ó ń gbìmọ̀ láti ré mi lẹ́pa.
5 Àwọn agbéraga ti dẹ tàkúté sílẹ̀ dè mí,wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi;wọ́n sì dẹ okùn sílẹ̀ fún mi lẹ́bàá ọ̀nà.
6 Mo wí fún OLUWA pé, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.”OLUWA, tẹ́tí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7 OLUWA, OLUWA mi, alágbára tíí gbani là,ìwọ ni o dáàbò bò mí ní ọjọ́ ogun.
8 OLUWA, má jẹ́ kí ọwọ́ àwọn eniyan burúkú tẹ ohun tí wọn ń wá;má jẹ́ kí èrò ọkàn wọn ṣẹ.
9 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ibi ẹnu àwọn tí ó yí mi kádà lé wọn lórí.
10 Jẹ́ kí ẹ̀yinná dà lé wọn lórí;jẹ́ kí wọn já sí kòtò, kí wọn má lè yọ.
11 Má jẹ́ kí abanijẹ́ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ilẹ̀ náà;jẹ́ kí oníwà ipá ko àgbákò kíákíá.
12 Mo mọ̀ pé OLUWA yóo gba ọ̀ràn olùpọ́njú rò,yóo sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní.
13 Dájúdájú, àwọn olódodo yóo máa fi ọpẹ́ fún ọ;àwọn olóòótọ́ yóo sì máa gbé níwájú rẹ.