Orin Dafidi 105 BM

Ọlọrun ati Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, ẹ pe orúkọ rẹ̀,ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè.

2 Ẹ kọrin sí i, ẹ kọ orin ìyìn sí i,ẹ sọ nípa gbogbo iṣẹ́ ribiribi rẹ̀.

3 Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn,kí ọkàn àwọn tí ń wá OLUWA ó máa yọ̀.

4 Ẹ wá ojurere OLUWA ati agbára rẹ̀,ẹ máa wá ojurere rẹ̀ nígbà gbogbo.

5 Ẹ ranti iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe,ẹ ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ati ìdájọ́ rẹ̀.

6 Ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀,ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.

7 OLUWA ni Ọlọrun wa,ìdájọ́ rẹ̀ kárí gbogbo ayé.

8 Títí lae ni ó ń ranti majẹmu rẹ̀,ó ranti àṣẹ tí ó pa fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran,

9 majẹmu tí ó bá Abrahamu dá,ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Isaaki,

10 tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí òfin,àní fún Israẹli gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé,

11 ó ní: “Ẹ̀yin ni n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún,yóo jẹ́ ìpín yín tí ẹ óo jogún.”

12 Nígbà tí wọ́n kéré ní iye,tí wọn kò tíì pọ̀ rárá, tí wọn sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà,

13 tí wọn ń káàkiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,láti ìjọba kan dé òmíràn,

14 kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn.

15 Ó ní, “Ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹni àmìòróró mi,ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe àwọn wolii mi níbi.”

16 Nígbà kan, ó mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà:ó ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ mọ́ wọn lẹ́nu.

17 Ṣugbọn ó kọ́ rán ọkunrin kan ṣáájú wọn,Josẹfu, ẹni tí a tà lẹ́rú.

18 Wọ́n so ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀,wọ́n ti ọrùn rẹ̀ bọ irin,

19 títí ìgbà tí ohun tí ó sọ fi ṣẹ,tí OLUWA sì jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

20 Ọba ranṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀,aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè sì dá a sílẹ̀.

21 Ó fi jẹ aláṣẹ ilé rẹ̀,ati alákòóso gbogbo nǹkan ìní rẹ̀;

22 láti máa ṣe olórí àwọn ìjòyè rẹ̀,kí ó sì máa kọ́ àwọn àgbà ìlú ní ìmọ̀.

23 Lẹ́yìn náà, Israẹli dé sí Ijipti,Jakọbu ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Hamu.

24 OLUWA mú kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ sí i,ó sì mú kí wọ́n lágbára ju àwọn ọ̀tá wọn lọ.

25 Ó yí àwọn ará Ijipti lọ́kàn pada,tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi kórìíra àwọn eniyan rẹ̀,tí wọ́n sì hùwà àrékérekè sí àwọn iranṣẹ rẹ̀.

26 Ó rán Mose, iranṣẹ rẹ̀,ati Aaroni, ẹni tí ó yàn.

27 Wọ́n ṣe iṣẹ́ àmì rẹ̀ ní ilẹ̀ náà,wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní ilẹ̀ Hamu,

28 Ọlọrun rán òkùnkùn, ilẹ̀ sì ṣú,ṣugbọn wọ́n ṣe oríkunkun sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,ó sì mú kí ẹja wọn kú.

30 Ọ̀pọ̀lọ́ ń tú jáde ní ilẹ̀ wọn,títí kan ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.

31 Ọlọrun sọ̀rọ̀, eṣinṣin sì rọ́ dé,iná aṣọ sì bo gbogbo ilẹ̀ wọn.

32 Ó rọ̀jò yìnyín lé wọn lórí,mànàmáná sì ń kọ káàkiri ilẹ̀ wọn.

33 Ó kọlu àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn,ó sì wó àwọn igi ilẹ̀ wọn.

34 Ó sọ̀rọ̀, àwọn eṣú sì rọ́ dé,ati àwọn tata tí kò lóǹkà;

35 wọ́n jẹ gbogbo ewé tí ó wà ní ilẹ̀ wọn,ati gbogbo èso ilẹ̀ náà.

36 Ó kọlu gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ wọn,àní, gbogbo àrẹ̀mọ ilẹ̀ wọn.

37 Lẹ́yìn náà, ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde,tàwọn ti fadaka ati wúrà,kò sì sí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yà kankan tí ó ṣe àìlera.

38 Inú àwọn ará Ijipti dùn nígbà tí wọ́n jáde,nítorí ẹ̀rù àwọn ọmọ Israẹli ń bà wọ́n.

39 OLUWA ta ìkùukùu bò wọ́n,ó sì pèsè iná láti tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lóru.

40 Wọ́n bèèrè ẹran, ó fún wọn ní àparò,ó sì pèsè oúnjẹ àjẹtẹ́rùn fún wọn láti ọ̀run.

41 Ó la àpáta, omi tú jáde,ó sì ṣàn ninu aṣálẹ̀ bí odò.

42 Nítorí pé ó ranti ìlérí mímọ́ rẹ̀,ati Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀.

43 Ó fi ayọ̀ kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde,ó kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jáde pẹlu orin.

44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,wọ́n sì jogún èrè iṣẹ́ àwọn eniyan náà.

45 Kí wọ́n lè máa mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ,kí wọ́n sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́.Ẹ yin OLUWA!