1 Ọlọrun ti jókòó ní ààyè rẹ̀ ninu ìgbìmọ̀ ọ̀run;ó sì ń ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run:
2 “Yóo ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin óo máa fi aiṣododo ṣe ìdájọ́,tí ẹ óo sì máa ṣe ojuṣaaju fún àwọn eniyan burúkú?
3 Ẹ ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn ọmọ aláìníbaba;ẹ sì máa ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tí ojú ń pọ́n ati àwọn talaka.
4 Ẹ gba talaka ati aláìní sílẹ̀,ẹ gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.”
5 Wọn kò ní ìmọ̀ tabi òye,wọ́n ń rìn kiri ninu òkùnkùn,títí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé fi mì tìtì.
6 Mo ní, “oriṣa ni yín,gbogbo yín ni ọmọ Ọ̀gá Ògo.
7 Ṣugbọn sibẹsibẹ, ẹ óo kú bí eniyan,ẹ ó sùn bí èyíkéyìí ninu àwọn ìjòyè.”
8 Dìde, Ọlọrun, ṣe ìdájọ́ ayé,nítorí tìrẹ ni gbogbo orílẹ̀-èdè!