1 OLUWA wí fún oluwa mi, ọba, pé,“Jókòó sí apá ọ̀tún mi,títí tí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹdi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”
2 OLUWA yóo na ọ̀pá àṣẹ rẹ tí ó lágbára láti Sioni.O óo jọba láàrin àwọn ọ̀tá rẹ.
3 Àwọn eniyan rẹ yóo fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀,lọ́jọ́ tí o bá ń kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ lórí òkè mímọ́.Àwọn ọ̀dọ́ yóo jáde tọ̀ ọ́ wá bí ìrì òwúrọ̀.
4 OLUWA ti búra, kò sì ní yí ọkàn rẹ̀ pada, pé,“Alufaa ni ọ́ títí lae,nípasẹ̀ Mẹlikisẹdẹki.”
5 OLUWA wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,yóo rún àwọn ọba wómúwómú ní ọjọ́ ibinu rẹ̀.
6 Yóo ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,ọpọlọpọ òkú ni yóo sì sùn ninu wọn;yóo sì run àwọn ìjòyè káàkiri ilẹ̀ ayé.
7 Ọba yóo mu omi ninu odò ẹ̀bá ọ̀nà,nítorí náà yóo sì gbé orí rẹ̀ sókè bí aṣẹ́gun.