1 Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA?Ṣé o óo wá gbàgbé mi laelae ni?Títí di ìgbà wo ni o óo fi ojú pamọ́ fún mi?
2 Títí di ìgbà wo ni ọkàn mi yóo gbọgbẹ́tí ìbànújẹ́ yóo gba ọkàn mi kan, ní gbogbo ìgbà?Títí di ìgbà wo ni àwọn ọ̀tá mi yóo máa yọ̀ mí?
3 Bojúwò mí, kí o sì dá mi lóhùn, OLUWA, Ọlọrun mi.Tan ìmọ́lẹ̀ sí ojú mi, kí n má baà sun oorun ikú.
4 Kí ọ̀tá mi má baà wí pé, “Mo ti rẹ́yìn rẹ̀.”Kí àwọn tí ó kórìíra mi má baà yọ̀ bí mo bá ṣubú.
5 Ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;n óo máa yọ̀ nítorí pé o óo gbà mí.
6 N óo máa kọrin sí ọ, OLUWA,nítorí o ṣeun fún mi lọpọlọpọ.