Orin Dafidi 94 BM

Ọlọrun Onídàájọ́ Gbogbo Ayé

1 OLUWA, ìwọ Ọlọrun ẹ̀san,ìwọ Ọlọrun ẹ̀san, fi agbára rẹ hàn!

2 Dìde, ìwọ onídàájọ́ ayé;san ẹ̀san èrè iṣẹ́ àwọn agbéraga fún wọn!

3 OLUWA, yóo ti pẹ́ tó?Àní, yóo ti pẹ́ tó tí àwọn eniyan burúkú yóo máa ṣe jàgínní?

4 Wọ́n ń fi ìgbéraga sọ̀rọ̀ jàbùjàbù,gbogbo àwọn aṣebi ní ń fọ́nnu.

5 Wọ́n ń rún àwọn eniyan rẹ mọ́lẹ̀, OLUWA,wọ́n ń pọ́n àwọn eniyan rẹ lójú.

6 Wọ́n ń pa àwọn opó ati àwọn àlejò,wọ́n sì ń pa àwọn aláìníbaba;

7 wọ́n ń sọ pé, “OLUWA kò rí wa;Ọlọrun Jakọbu kò ṣàkíyèsí wa.”

8 Ẹ jẹ́ kí ó ye yín,ẹ̀yin tí ẹ ya òpè jùlọ láàrin àwọn eniyan!Ẹ̀yin òmùgọ̀, nígbà wo ni ẹ óo gbọ́n?

9 Ṣé ẹni tí ó dá etí, ni kò ní gbọ́ràn?Àbí ẹni tí ó dá ojú, ni kò ní ríran?

10 Ṣé ẹni tí ń jẹ àwọn orílẹ̀-èdè níyà,ni kò ní jẹ yín níyà?Àbí ẹni tí ń fún eniyan ní ìmọ̀, ni kò ní ní ìmọ̀?

11 OLUWA mọ èrò ọkàn ọmọ eniyan,ó mọ̀ pé afẹ́fẹ́ lásán ni.

12 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o bá báwí, OLUWA,tí o sì kọ́ ní òfin rẹ,

13 kí ó lè sinmi lọ́wọ́ ọjọ́ ìṣòro,títí tí a ó fi gbẹ́ kòtò fún eniyan burúkú.

14 Nítorí OLUWA kò ní kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀;kò ní ṣá àwọn eniyan ìní rẹ̀ tì;

15 nítorí pé ìdájọ́ òtítọ́ yóo pada jẹ́ ìpín àwọn olódodo,àwọn olóòótọ́ yóo sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

16 Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn eniyan burúkú?Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn aṣebi?

17 Bí kì í bá ṣe pé OLUWA ràn mí lọ́wọ́,ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní isà òkú.

18 Nígbà tí mo rò pé, “Ẹsẹ̀ mi ti yọ̀,”OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni ó gbé mi ró.

19 Nígbà tí àìbàlẹ̀ ọkàn mi pọ̀ pupọ,ìwọ ni o tù mí ninu, tí o dá mi lọ́kàn le.

20 Ǹjẹ́ o lè ní àjọṣe pẹlu àwọn ìkà aláṣẹ,àwọn tí ń fi òfin gbé ìwà ìkà ró?

21 Wọ́n para pọ̀ láti gba ẹ̀mí olódodo;wọ́n sì dá ẹjọ́ ikú fún aláìṣẹ̀.

22 Ṣugbọn OLUWA ti di ibi ìsádi mi,Ọlọrun mi sì ti di àpáta ààbò mi.

23 Yóo san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn,yóo pa wọ́n run nítorí ìwà ìkà wọn.OLUWA Ọlọrun wa yóo pa wọ́n run.