1 Mo ké pe Ọlọrun fún ìrànlọ́wọ́,mo kígbe pe Ọlọrun kí ó lè gbọ́ tèmi.
2 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi, mo wá OLUWA;ní òru, mo tẹ́wọ́ adura láìkáàárẹ̀,ṣugbọn n kò rí ìtùnú.
3 Mo ronú nípa Ọlọrun títí, mò ń kérora;mo ṣe àṣàrò títí, ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì.
4 OLUWA, o ò jẹ́ kí n dijú wò ní gbogbo òrumo dààmú tóbẹ́ẹ̀ tí n kò le sọ̀rọ̀.
5 Mo ranti ìgbà àtijọ́,mo ranti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.
6 Mo ronú jinlẹ̀ lóru,mo ṣe àṣàrò, mo yẹ ọkàn mi wò.
7 Ṣé Ọlọrun yóo kọ̀ wá sílẹ̀ títí lae ni;àbí inú rẹ̀ kò tún ní dùn sí wa mọ́?
8 Ṣé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ti pin títí lae ni;àbí ìlérí rẹ̀ ti dópin patapata?
9 Ṣé Ọlọrun ti gbàgbé láti máa ṣoore ni;àbí ó ti fi ibinu pa ojú àánú rẹ̀ dé?
10 Nígbà náà ni mo wí pé, “Ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́ ni péỌ̀gá Ògo kò jẹ́wọ́ agbára mọ́.”
11 N óo ranti àwọn iṣẹ́ OLUWA,àní, n óo ranti àwọn iṣẹ́ ìyanu ìgbàanì.
12 N óo máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ;n óo sì máa ronú lórí àwọn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe.
13 Ọlọrun, mímọ́ ni ọ̀nà rẹ;oriṣa wo ni ó tó Ọlọrun wa?
14 Ìwọ ni Ọlọrun tí ń ṣe ohun ìyanu;o ti fi agbára rẹ hàn láàrin àwọn eniyan.
15 O ti fi agbára rẹ gba àwọn eniyan rẹ là;àní, àwọn ọmọ Jakọbu ati Josẹfu.
16 Nígbà tí omi òkun rí ọ, Ọlọrun,àní, nígbà tí omi òkun fi ojú kàn ọ́,ẹ̀rù bà á;ibú omi sì wárìrì.
17 Ìkùukùu da omi òjò sílẹ̀,ojú ọ̀run sán ààrá;mànàmáná ń kọ yẹ̀rì káàkiri.
18 Ààrá ń sán kíkankíkan ní ojú ọ̀run,mànàmáná ń kọ yànràn, gbogbo ayé sì mọ́lẹ̀;ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì.
19 Ọ̀nà rẹ wà lójú omi òkun,ipa ọ̀nà rẹ la omi òkun ńlá já;sibẹ ẹnìkan kò rí ipa ẹsẹ̀ rẹ.
20 O kó àwọn eniyan rẹ jáde bí agbo ẹran,o fi Mose ati Aaroni ṣe olórí wọn.