Orin Dafidi 144 BM

Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun

1 Ìyìn ni fún OLUWA, àpáta mi,ẹni tí ó kọ́ mi ní ìjà jíjà,tí ó kọ́ mi ní iṣẹ́ ogun.

2 Òun ni àpáta mi, ààbò mi, odi mi, olùdáǹdè mi,asà mi, ẹni tí mo sá di.Òun ni ó tẹrí àwọn eniyan ba lábẹ́ rẹ̀.

3 OLUWA, kí ni eniyan jẹ́, tí o fi ń náání rẹ̀?Kí sì ni ọmọ eniyan tí o fi ń ranti rẹ̀?

4 Eniyan dàbí èémí,ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí òjìji tí ń kọjá lọ.

5 OLUWA, fa ojú ọ̀run wá sílẹ̀, kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,fọwọ́ kan àwọn òkè ńlá, kí wọ́n máa rú èéfín.

6 Jẹ́ kí mànàmáná kọ, kí o sì tú wọn ká,ta ọfà rẹ, kí o tú wọn ká.

7 Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti òkè,kí o yọ mí ninu ibú omi;kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,

8 tí ẹnu wọn kún fún irọ́,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké.

9 Ọlọrun, n óo kọ orin titun sí ọ,n óo fi hapu olókùn mẹ́wàá kọrin sí ọ.

10 Ìwọ ni ò ń fún àwọn ọba ní ìṣẹ́gun,tí o sì gba Dafidi, iranṣẹ rẹ, là.

11 Gbà mí lọ́wọ́ idà ìkà,gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,tí ẹnu wọ́n kún fún irọ́,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké.

12 Ní ìgbà èwe àwọn ọdọmọkunrin wa,jẹ́ kí wọ́n dàbí igi tí a gbìn tí ó dàgbà,kí àwọn ọdọmọbinrin wa dàbí òpó igun ilé,tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí bíi ti ààfin ọba.

13 Kí àká wa kún fún oniruuru oúnjẹ,kí àwọn aguntan wa bí ẹgbẹẹgbẹrun,àní, ẹgbẹẹgbaarun ninu pápá oko wa.

14 Kí àwọn mààlúù wa lóyún,kí wọ́n má rọ́nú, kí wọ́n má bí òkúmọ;kí ó má sí ariwo àjálù ní ìgboro wa.

15 Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí ó ní irú ibukun yìí;ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn.