Orin Dafidi 104 BM

Yíyin Ẹlẹ́dàá

1 Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,OLUWA, Ọlọrun mi, ó tóbi pupọ,ọlá ati iyì ni ó wọ̀ bí ẹ̀wù.

2 Ó fi ìmọ́lẹ̀ bora bí aṣọ,ó ta ojú ọ̀run bí ẹni taṣọ.

3 Ìwọ tí o tẹ́ àjà ibùgbé rẹ sórí omi,tí o fi ìkùukùu ṣe kẹ̀kẹ́ ogun rẹ,tí o sì ń lọ geere lórí afẹ́fẹ́.

4 Ìwọ tí o fi ẹ̀fúùfù ṣe iranṣẹ,tí o sì fi iná ati ahọ́n iná ṣe òjíṣẹ́ rẹ.

5 Ìwọ tí o gbé ayé kalẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ rẹ̀,tí kò sì le yẹ̀ laelae.

6 O fi ibú omi bò ó bí aṣọ,omi sì borí àwọn òkè ńlá.

7 Nígbà tí o bá wọn wí, wọ́n sá,nígbà tí o sán ààrá, wọ́n sá sẹ́yìn.

8 Wọ́n ṣàn kọjá lórí òkèlọ sí inú àfonífojì,sí ibi tí o yàn fún wọn.

9 O ti pa ààlà tí wọn kò gbọdọ̀ kọjá,kí wọn má baà tún bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́.

10 Ìwọ ni o mú kí àwọn orísun máa tú omi jáde ní àfonífojì;omi wọn sì ń ṣàn láàrin àwọn òkè.

11 Ninu omi wọn ni gbogbo ẹranko tí ń mu,ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń rẹ òùngbẹ.

12 Lẹ́bàá orísun wọnyini àwọn ẹyẹ ń gbé,wọ́n sì ń kọrin lórí igi.

13 Láti ibùgbé rẹ lókè ni o tí ń bomi rin àwọn òkè ńlá.Ilẹ̀ sì mu àmutẹ́rùn nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

14 Ó ń mú kí koríko dàgbà fún àwọn ẹran láti jẹ,ati ohun ọ̀gbìn fún ìlò eniyan,kí ó lè máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀;

15 ati ọtí waini tí ń mú inú eniyan dùn,ati epo tí ń mú ojú eniyan dán,ati oúnjẹ tí ń fún ara lókun.

16 Àwọn igi OLUWA ń mu omi ní àmutẹ́rùn,àní àwọn igi kedari Lẹbanoni tí ó gbìn.

17 Lórí wọn ni àwọn ẹyẹ ń tẹ́ ìtẹ́wọn sí,àkọ̀ sì ń kọ́ ilé rẹ̀ sórí igi firi.

18 Òkè gíga ni ilé ewúrẹ́ igbó,abẹ́ àpáta sì ni ibùgbé ehoro.

19 O dá òṣùpá láti máa sàmì àkókò,oòrùn sì mọ àkókò wíwọ̀ rẹ̀.

20 O mú kí òkùnkùn ṣú, alẹ́ sì lẹ́,gbogbo ẹranko ìgbẹ́ sìń jẹ kiri.

21 Àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ń bú fún ìjẹ,wọ́n ń wo ojú Ọlọrun fún oúnjẹ.

22 Nígbà tí oòrùn bá là, wọn á wọ́ lọ;wọn á lọ dùbúlẹ̀ sinu ihò wọn.

23 Ọmọ eniyan á sì jáde lọ síbi iṣẹ́ rẹ̀,á lọ síbi làálàá rẹ̀ títí di àṣáálẹ́.

24 OLUWA, ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ!Ọgbọ́n ni o fi dá gbogbo wọn.Ayé kún fún àwọn ẹ̀dá rẹ.

25 Ẹ wo òkun bí ó ti tóbi tí ó sì fẹ̀,ó kún fún ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá,nǹkan abẹ̀mí kéékèèké ati ńláńlá.

26 Ibẹ̀ ni ọkọ̀ ojú omi ń gbà lọ,ati Lefiatani tí o dá láti máa ṣeré ninu òkun.

27 Ojú rẹ ni gbogbo wọn ń wò,fún ìpèsè oúnjẹ ní àkókò.

28 Nígbà tí o bá fún wọn, wọn á kó o jọ,nígbà tí o bá la ọwọ́,wọn á jẹ ohun dáradára ní àjẹyó.

29 Bí o bá fojú pamọ́,ẹ̀rù á bà wọ́n,bí o bá gba ẹ̀mí wọn, wọn á kú,wọn á sì pada di erùpẹ̀.

30 Nígbà tí o rán ẹ̀mí rẹ jáde,wọ́n di ẹ̀dá alààyè,o sì sọ orí ilẹ̀ di ọ̀tun.

31 Kí ògo OLUWA máa wà títí lae,kí OLUWA máa yọ̀ ninu iṣẹ́ rẹ̀.

32 Ẹni tí ó wo ilẹ̀, tí ilẹ̀ mì tìtì,tí ó fọwọ́ kan òkè, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ èéfín.

33 N óo kọrin ìyìn sí OLUWAníwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè.N óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi,níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀mí mi bá ń bẹ.

34 Kí àṣàrò ọkàn mi kí ó dùn mọ́ ọn ninunítorí mo láyọ̀ ninu OLUWA.

35 Kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ parẹ́ lórí ilẹ̀ ayé,kí àwọn eniyan burúkú má sí mọ́.Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi!Yin OLUWA!