1 Ẹ yin OLUWA!Ẹ yin Ọlọrun ninu ibi mímọ́ rẹ̀;ẹ yìn ín ninu òfuurufú rẹ̀ tí ó lágbára.
2 Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ ńlá rẹ̀;ẹ yìn ín nítorí pé ó tóbi pupọ.
3 Ẹ fi ariwo fèrè yìn ín;ẹ fi fèrè ati hapu yìn ín.
4 Ẹ fi ìlù ati ijó yìn ín;ẹ fi gòjé ati dùùrù yìn ín.
5 Ẹ fi aro olóhùn òkè yìn ín;ẹ fi aro olóhùn gooro yìn ín.
6 Kí gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí yin OLUWA! Ẹ yin OLUWA!