1 Gbọ́ adura mi, OLUWA;kí o sì jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ.
2 Má yọwọ́ lọ́ràn mi lọ́jọ́ ìṣòro!Dẹtí sí adura mi;kí o sì tètè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ké pè ọ́.
3 Nítorí ọjọ́ ayé mi ń kọjá lọ bí èéfín,eegun mi gbóná bí iná ààrò.
4 Ìdààmú bá ọkàn mi, mo rọ bíi koríko,tóbẹ́ẹ̀ tí mo gbàgbé láti jẹun.
5 Nítorí igbe ìrora mi,mo rù kan eegun.
6 Mo dàbí igúnnugún inú aṣálẹ̀,àní, bí òwìwí inú ahoro.
7 Mo dùbúlẹ̀ láìlè sùn,mo dàbí ẹyẹ tí ó dá wà lórí òrùlé.
8 Àwọn ọ̀tá ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru,àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi ń fi orúkọ mi ṣépè.
9 Mò ń jẹ eérú bí oúnjẹ,mo sì ń mu omijé mọ́ omi
10 nítorí ìrúnú ati ibinu rẹ;o gbé mi sókè,o sì jù mí nù.
11 Ọjọ́ ayé mi ń lọ bí òjìji àṣáálẹ́,mo sì ń rọ bíi koríko.
12 Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ OLUWA gúnwà títí lae,ọlá rẹ sì wà láti ìran dé ìran.
13 Ìwọ óo dìde, o óo sì ṣàánú Sioni,nítorí ó tó àkókò láti fi ojú àánú wò ó.Àkókò tí o dá tó.
14 Nítorí àwọn òkúta rẹ̀ ṣe iyebíye lójú àwọn iranṣẹ rẹ,àánú rẹ̀ sì ṣeni bí ó tilẹ̀ ti wó dà sinu erùpẹ̀.
15 Àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA,gbogbo ọba ayé ni yóo sì máa bẹ̀rù ògo rẹ̀.
16 Nítorí OLUWA yóo tún Sioni kọ́,yóo sì fara hàn ninu ògo rẹ̀.
17 Yóo gbọ́ adura àwọn aláìní,kò sì ní kẹ́gàn ẹ̀bẹ̀ wọn.
18 Kí ẹ kọ èyí sílẹ̀ fún ìran tí ń bọ̀,kí àwọn ọmọ tí a kò tíì bí lè máa yin OLUWA,
19 pé OLUWA bojú wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀,láti ọ̀run ni ó ti bojú wo ayé;
20 láti gbọ́ ìkérora àwọn ìgbèkùn,ati láti dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sílẹ̀.
21 Kí á lè pòkìkí orúkọ OLUWA ní Sioni,kí á sì máa yìn ín lógo ní Jerusalẹmu,
22 nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá péjọ tàwọn tọba wọn,láti sin OLUWA.
23 Ó ti gba agbára mi ní àìpé ọjọ́,ó ti gé ọjọ́ ayé mi kúrú.
24 Mo ní, “Áà! Ọlọrun mi, má mú mi kúrò láyé láìpé ọjọ́,ìwọ tí ọjọ́ ayé rẹ kò lópin.”
25 Láti ìgbà laelae ni o ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sì ni ọ̀run.
26 Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ yóo wà títí lae;gbogbo wọn yóo gbó bí aṣọ,o óo pààrọ̀ wọn bí aṣọ;wọn yóo sì di ohun ìpatì.
27 Ṣugbọn ìwọ wà bákan náà,ọjọ́ ayé rẹ kò sì lópin.
28 Ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ yóo ní ibùgbé;bẹ́ẹ̀ ni arọmọdọmọ wọn yóo fẹsẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ.