Orin Dafidi 39 BM

Ìráhùn Ẹni tí Ìyà ń Jẹ

1 Mo ní, “Èmi óo máa ṣọ́ra,kí n má baà fi ahọ́n mi dẹ́ṣẹ̀;n óo kó ẹnu mi ní ìjánu,níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan burúkú bá wà nítòsí.”

2 Mo dákẹ́, n ò sọ nǹkankan;n ò tilẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ rere pàápàá;sibẹ ìpọ́njú mi ń pọ̀ sí i

3 ìdààmú dé bá ọkàn mi.Bí mo ti ń ronú, ọkàn mi dàrú;mo bá sọ̀rọ̀ jáde, mo ní:

4 “OLUWA, jẹ́ kí n mọ òpin ayé mi,ati ìwọ̀nba ọjọ́ ayé mi,kí n lè mọ̀ pé ayé mi ń sáré kọjá lọ.”

5 Wò ó, o ti ṣe ọjọ́ mi ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ mélòó kan,ọjọ́ ayé mi kò sì tó nǹkankan ní ojú rẹ;dájúdájú, ọmọ eniyan dàbí afẹ́fẹ́ lásán.

6 Dájúdájú, eniyan ń káàkiri bí òjìji,asán sì ni gbogbo làálàá rẹ̀;eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ ṣá,láìmọ ẹni tí yóo kó o lọ.

7 Wàyí ò, OLUWA, kí ló kù tí mo gbójú lé?Ìwọ ni mo fẹ̀yìn tì.

8 Gbà mí ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìrékọjá mi;má sọ mí di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn òmùgọ̀.

9 Mo dákẹ́, n kò ya ẹnu mi;nítorí pé ìwọ ni o ṣe é.

10 Dáwọ́ ẹgba rẹ dúró lára mi,mo ti fẹ́rẹ̀ kú nítorí ìyà tí o fi ń jẹ mí.

11 Nígbà tí o bá jẹ eniyan níyàpẹlu ìbáwí nítorí ẹ̀ṣẹ̀,ìwọ á ba ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún un jẹ́ bíi kòkòrò aṣọ.Dájúdájú, afẹ́fẹ́ lásán ni eniyan.

12 “OLUWA, gbọ́ adura mi,tẹ́tí sí igbe mi,má dágunlá sí ẹkún mi,nítorí pé àlejò rẹ, tí ń rékọjá lọ ni mo jẹ́;àjèjì sì ni mí, bíi gbogbo àwọn baba mi.

13 Mú ojú ìbáwí kúrò lára mi,kí inú mi lè dùn kí n tó kọjá lọ;àní, kí n tó ṣe aláìsí.”