1 Ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi ògo fún OLUWA,ẹ gbé agbára rẹ̀ lárugẹ.
2 Ẹ fún OLUWA ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀,ẹ máa sin OLUWA ninu ẹwà mímọ́ rẹ̀.
3 À ń gbọ́ ohùn OLUWA lójú omi òkun,Ọlọrun ológo ń sán ààrá,Ọlọrun ń sán ààrá lójú alagbalúgbú omi.
4 Ohùn OLUWA lágbára,ohùn OLUWA kún fún ọlá ńlá.
5 Ohùn OLUWA ń fọ́ igi kedari,OLUWA ń fọ́ igi kedari ti Lẹbanoni.
6 Ó ń mú kí òkè Lẹbanoni ta pọ́núnpọ́nún bí ọmọ mààlúù,ó sì mú kí òkè Sirioni máa fò bí akọ ọmọ mààlúù-igbó.
7 Ohùn OLUWA ń yọ iná lálá.
8 Ohùn OLUWA ń mi aṣálẹ̀;OLUWA ń mi aṣálẹ̀ Kadeṣi.
9 Ohùn OLUWA a máa mú abo àgbọ̀nrín bí,a máa wọ́ ewé lára igi oko;gbogbo eniyan ń kígbe ògo rẹ̀ ninu Tẹmpili rẹ̀.
10 OLUWA jókòó, ó gúnwà lórí ìkún omi;OLUWA jókòó, ó gúnwà bí ọba títí lae.
11 OLUWA yóo fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára;OLUWA yóo fún wọn ní ibukun alaafia.