Orin Dafidi 83 BM

Adura Ìṣẹ́gun

1 Ọlọrun, má dákẹ́;má wòran; Ọlọrun má dúró jẹ́ẹ́!

2 Wò ó! Àwọn ọ̀tá rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ;àwọn tí ó kórìíra rẹ sì ń yájú sí ọ.

3 Wọ́n pète àrékérekè sí àwọn eniyan rẹ;wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ sí àwọn tí ó sá di ọ́.

4 Wọ́n ní, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa orílẹ̀-èdè wọn run;kí á má ranti orúkọ Israẹli mọ́!”

5 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ pète pèrò;wọ́n dá majẹmu láti dojú kọ ọ́.

6 Àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Iṣimaeli,àwọn ará Moabu, ati àwọn ọmọ Hagiri,

7 àwọn ará Gebali, àwọn ọmọ Amoni, ati àwọn ọmọ Amaleki,àwọn ará Filistia ati àwọn tí ń gbé Tire.

8 Àwọn ará Asiria pàápàá ti dara pọ̀ mọ́ wọn;àwọn ni alátìlẹ́yìn àwọn ọmọ Lọti.

9 Ṣe wọ́n bí o ti ṣe àwọn ará Midiani,bí o ti ṣe Sisera ati Jabini ni odò Kiṣoni,

10 àwọn tí o parun ní Endori,tí wọ́n di ààtàn lórí ilẹ̀.

11 Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí o ti ṣe Orebu ati Seebu;ṣe àwọn ìjòyè wọn bí o ti ṣe Seba ati Salumuna,

12 àwọn tí ó wí pé,“Ẹ jẹ́ kí á mú lára ilẹ̀ Ọlọrunkí á sọ ọ́ di tiwa.”

13 Ọlọrun mi, ṣe wọ́n bí ààjà tíí ṣe ewé,àní, bí afẹ́fẹ́ tíí ṣe fùlùfúlù.

14 Bí iná tíí jó igbó,àní, bí ọwọ́ iná sì ṣe ń jó òkè kanlẹ̀,

15 bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ìjì rẹ lé wọn,kí o sì fi ààjà rẹ dẹ́rù bà wọ́n.

16 Da ìtìjú bò wọ́n,kí wọn lè máa wá ọ kiri, OLUWA.

17 Jẹ́ kí ojú tì wọ́n, kí ìdààmú dé bá wọn títí lae,kí wọn sì ṣègbé ninu ìtìjú.

18 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ nìkan,tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA,ni Ọ̀gá Ògo lórí gbogbo ayé.