1 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí a dárí ìrékọjá rẹ̀ jì,tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.
2 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí OLUWA kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn,tí ẹ̀tàn kò sì sí ninu ọkàn rẹ̀.
3 Nígbà tí n kò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi,ó rẹ̀ mí wá láti inú,nítorí kíkérora tí mò ń kérora ní gbogbo ìgbà.
4 Nítorí tọ̀sán-tòru ni o fi ń jẹ mí níyà;gbogbo agbára mi ló lọ háú,bí omi tíí gbẹ lákòókò ẹ̀ẹ̀rùn.
5 Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ;n kò sì fi àìdára mi pamọ́ fún ọ.Mo ní, “Èmi óo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Oluwa,”o sì dáríjì mí.
6 Nítorí náà, kí gbogbo olódodo máa gbadura sí ọ;ní àkókò tí ìpọ́njú bá ń yí lura wọn bí ìṣàn omi ńlá,kò ní dé ọ̀dọ̀ wọn.
7 Ìwọ ni ibi ìsásí mi;o pa mí mọ́ kúrò ninu ìṣòro;o sì fi ìgbàlà yí mi ká.
8 N óo kọ́ ọ, n óo sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tí o óo rìn;n óo máa gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn;n óo sì máa mójútó ọ.
9 Má ṣe dàbí ẹṣin tabi ìbaaka,tí kò ni ọgbọ́n ninu,tí a gbọdọ̀ kó ìjánu sí lẹ́nukí ó tó lè gbọ́ ti oluwa rẹ̀.
10 Ìrora pọ̀ fún àwọn eniyan burúkú,ṣugbọn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni ó yí àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA ká.
11 Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA;ẹ fò fún ayọ̀, ẹ̀yin olódodo;kí ẹ sì hó fún ayọ̀, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn mímọ́.