Orin Dafidi 132 BM

Majẹmu Ọlọrun pẹlu Ìdílé Dafidi

1 OLUWA, ranti gbogbo ìyà tí Dafidi fara dà.

2 Ranti bí ó ṣe búra fún OLUWA,tí ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu,

3 tí ó ní, “N kò ní wọ inú ilé mi,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní bọ́ sí orí ibùsùn mi;

4 n kò ní sùn,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní tòògbé,

5 títí tí n óo fi wá ààyè fún OLUWA,àní, tí n óo fi pèsè ibùgbé fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu.”

6 A gbúròó rẹ̀ ní Efurata,a rí i ní oko Jearimu.

7 “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùgbé rẹ̀;ẹ jẹ́ kí á lọ wólẹ̀ níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.”

8 Dìde, OLUWA, lọ sí ibi ìsinmi rẹ,tìwọ ti àpótí agbára rẹ.

9 Jẹ́ kí àwọn alufaa rẹ wọ ẹ̀wù òdodo,kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ sì máa kọrin ayọ̀.

10 Nítorí ti Dafidi, iranṣẹ rẹ,má jẹ́ kí ẹni tí a fi òróró rẹ yàn yíjú kúrò lára rẹ.

11 OLUWA ti ṣe ìbúra tí ó dájú fún Dafidi,èyí tí kò ní yipada; ó ní,“Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹni n óo gbé ka orí ìtẹ́ rẹ.

12 Bí àwọn ọmọ rẹ bá pa majẹmu mi mọ́,tí wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí n óo fi lélẹ̀ fún wọn,àwọn ọmọ tiwọn náà óo jókòó lórí ìtẹ́ rẹ títí lae.”

13 Nítorí OLUWA ti yan Sioni;ó fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀:

14 Ó ní, “Ìhín ni ibi ìsinmi mi títí lae,níhìn-ín ni n óo máa gbé, nítorí pé ó wù mí.

15 N óo bù sí oúnjẹ rẹ̀ lọpọlọpọ;n óo fi oúnjẹ tẹ́ àwọn aláìní ibẹ̀ lọ́rùn.

16 N óo gbé ẹ̀wù ìgbàlà wọ àwọn alufaa rẹ̀,àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀ yóo sì kọrin ayọ̀.

17 Níbẹ̀ ni n óo ti fún Dafidi ní agbára;mo ti gbé àtùpà kalẹ̀ fún ẹni tí mo fi òróró yàn.

18 N óo da ìtìjú bo àwọn ọ̀tá rẹ̀ bí aṣọ,ṣugbọn adé orí rẹ̀ yóo máa tàn yinrinyinrin.”