Orin Dafidi 68 BM

Orin ìṣẹ́gun ti Orílẹ̀-Èdè

1 Kí Ọlọrun dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ tú ká.Kí àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ sá níwájú rẹ̀.

2 Bí èéfín tií pòórá,bẹ́ẹ̀ ni kí wọn parẹ́;bí ìda tií yọ́ níwájú iná,bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn eniyan burúkú parun níwájú Ọlọrun.

3 Ṣugbọn kí inú àwọn olódodo máa dùn,kí wọn máa yọ̀ níwájú Ọlọrun;kí wọn máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.

4 Ẹ kọrin sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ̀,ẹ pòkìkí ẹni tí ń gun ìkùukùu lẹ́ṣin.OLUWA ni orúkọ rẹ̀;ẹ máa yọ̀ níwájú rẹ̀.

5 Baba àwọn aláìníbaba ati olùgbèjà àwọn opó ni Ọlọrun,ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́.

6 Ọlọrun, olùpèsè ibùjókòó fún àlejò tí ó nìkan wà;ẹni tí ó kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde sinu ìdẹ̀ra,ṣugbọn ó sì fi àwọn ọlọ̀tẹ̀ sílẹ̀ ninu ilẹ̀ gbígbẹ.

7 Ọlọrun, nígbà tí ò ń jáde lọ níwájú àwọn eniyan rẹ,nígbà tí ò ń yan la aṣálẹ̀ já,

8 ilẹ̀ mì tìtì, ọ̀run pàápàá rọ òjò,níwájú Ọlọrun, Ọlọrun Sinai,àní, níwájú Ọlọrun Israẹli.

9 Ọlọrun, ọpọlọpọ ni òjò tí o rọ̀ sílẹ̀;o sì mú ilẹ̀ ìní rẹ tí ó ti gbẹ pada bọ̀ sípò.

10 Àwọn eniyan rẹ rí ibùgbé lórí rẹ̀;Ọlọrun, ninu oore ọwọ́ rẹ, o pèsè fún àwọn aláìní.

11 OLUWA fọhùn,ogunlọ́gọ̀ sì ni àwọn tí ó kéde ọ̀rọ̀ rẹ̀.

12 Gbogbo àwọn ọba ni ó sá tàwọn tọmọ ogun wọn;àwọn obinrin tí ó wà nílé,

13 ati àwọn tí ó wà ní ibùjẹ ẹran rí ìkógun pín:fadaka ni wọ́n yọ́ bo apá ère àdàbà;wúrà dídán sì ni wọ́n yọ́ bo ìyẹ́ rẹ̀.

14 Nígbà tí Olodumare tú àwọn ọba ká,ní òkè Salimoni, yìnyín bọ́.

15 Áà! Òkè Baṣani, òkè ńlá;Áà! Òkè Baṣani, òkè olórí pupọ.

16 Ẹ̀yin òkè olórí pupọ,kí ló dé tí ẹ̀ ń fi ìlara wo òkè tí Ọlọrun fẹ́ràn láti máa gbé,ibi tí OLUWA yóo máa gbé títí lae?

17 OLUWA sọ̀kalẹ̀ láti òkè Sinai sí ibi mímọ́ rẹ̀pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun kẹ̀kẹ́ ogun,ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun.

18 Ó gun òkè gíga,ó kó àwọn eniyan nígbèkùn;ó gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn eniyan,ati lọ́wọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ pàápàá.OLUWA Ọlọrun yóo máa gbébẹ̀.

19 Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun ìgbàlà wa,tí ń bá wa gbé ẹrù wa lojoojumọ.

20 Ọlọrun tí ń gbani là ni Ọlọrun wa;OLUWA Ọlọrun ni ń yọni lọ́wọ́ ikú.

21 Dájúdájú, OLUWA yóo fọ́ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀;yóo fọ́ àtàrí àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀.

22 OLUWA ní,“N óo kó wọn pada láti Baṣani,n óo kó wọn pada láti inú ibú omi òkun,

23 kí ẹ lè fi ẹsẹ̀ wọ́ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá yín,kí àwọn ajá yín lè lá ẹ̀jẹ̀ wọn bí ó ti wù wọ́n.”

24 A ti rí ọ, Ọlọrun, bí o tí ń yan lọ,pẹlu ọ̀wọ́ èrò tí ń tẹ̀lé ọ lẹ́yìn.Ẹ wo Ọlọrun mi, ọba mi,bí ó ti ń yan wọ ibi mímọ́ rẹ̀,

25 àwọn akọrin níwájú,àwọn onílù lẹ́yìn,àwọn ọmọbinrin tí ń lu samba láàrin.

26 “Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọrun ninu àwùjọ eniyan,ẹ̀yin ìran Israẹli, ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA.”

27 Ẹ wo Bẹnjamini tí ó kéré jù níwájú,ẹ wo ogunlọ́gọ̀ àwọn ìjòyè Juda,ẹ wo àwọn ìjòyè Sebuluni ati ti Nafutali.

28 Fi agbára rẹ hàn, Ọlọrun,fi agbára tí o ti fi jà fún wa hàn.

29 Nítorí Tẹmpili rẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu,àwọn ọba yóo gbé ẹ̀bùn wá fún ọ.

30 Bá àwọn ẹranko ẹ̀dá tí ń gbé inú èèsún ní Ijipti wí;àwọn akọ mààlúù, láàrin agbo ẹran àwọn orílẹ̀-èdè.Tẹ àwọn tí ó fẹ́ràn owó mọ́lẹ̀;fọ́n àwọn orílẹ̀-èdè tí ó fẹ́ràn ogun ká.

31 Jẹ́ kí àwọn ikọ̀ wá láti Ijipti,kí àwọn ará Kuṣi tẹ́wọ́ adura sí Ọlọrun.

32 Ẹ kọ orin sí Ọlọrun ẹ̀yin ìjọba ayé;ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA.

33 Ẹni tí ń gun awọsanma lẹ́ṣin, àní awọsanma àtayébáyé;ẹ gbọ́ bí ó ṣe ń sán ààrá, ẹ gbọ́ ohùn alágbára.

34 Ẹ bu ọlá fún Ọlọrun,ẹni tí ògo rẹ̀ wà lórí Israẹli;tí agbára rẹ̀ sì hàn lójú ọ̀run.

35 Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni Ọlọrun ní ibi mímọ́ rẹ̀,Ọlọrun Israẹli;òun ni ó ń fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ọlá ati agbára.Ìyìn ni fún Ọlọrun!