1 Mo fẹ́ràn rẹ, OLUWA, agbára mi.
2 OLUWA ni àpáta mi, ibi ààbò mi, ati olùgbàlà mi;Ọlọrun mi, àpáta mi, ninu ẹni tí ààbò mi wà.Òun ni asà mi, ìwo ìgbàlà mi ati ibi ìsásí mi.
3 Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ,ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
4 Ikú wé mọ́ mi bí okùn,ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi rírú omi.
5 Isà òkú yí mi ká,tàkúté ikú sì dojú kọ mí.
6 Ninu ìpọ́njú mi mo ké pe OLUWA,Ọlọrun mi ni mo ké pè.Ó gbọ́ ohùn mi láti inú ilé mímọ́ rẹ̀,ó sì tẹ́tí sí igbe mi.
7 Ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì,ìpìlẹ̀ àwọn òkè mì jìgìjìgì;wọ́n wárìrì nítorí tí ó bínú.
8 Èéfín ṣẹ́ jáde láti ihò imú rẹ̀,iná ajónirun yọ jáde láti ẹnu rẹ̀;ẹ̀yinná sì ń jò bùlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
9 Ó dẹ ojú ọ̀run sílẹ̀, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá,ìkùukùu tó ṣókùnkùn biribiri sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
10 Ó gun orí Kerubu, ó sì fò,ó fò lọ sókè lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
11 Ó fi òkùnkùn bora bí aṣọ,ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì kún fún omini ó fi ṣe ìbòrí.
12 Ninu ìmọ́lẹ̀ níwájú rẹ,ẹ̀yinná ati yìnyín ń fọ́n jáde,láti inú ìkùukùu.
13 OLUWA sán ààrá láti ọ̀run,Ọ̀gá Ògo fọhùn, òjò dídì ati ẹ̀yinná sì fọ́n jáde.
14 Ó ta ọfà rẹ̀ jáde, ó sì fọ́n wọn ká,ó jẹ́ kí mànàmáná kọ, ó sì tú wọn ká.
15 Nígbà náà ni ìsàlẹ̀ òkun hàn ketekete,ìpìlẹ̀ ayé sì fojú hàn gbangba nítorí ìbáwí rẹ, OLUWA,ati nítorí agbára èémí ihò imú rẹ.
16 Ó nawọ́ láti òkè wá, ó sì dì mí mú,ó fà mí jáde láti inú ibú omi.
17 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi tí ó lágbára,ati lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi;nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ.
18 Wọ́n gbógun tì mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi,ṣugbọn OLUWA ni aláfẹ̀yìntì mi.
19 Ó mú mi jáde wá síbi tí ó láàyè,ó yọ mí jáde nítorí tí inú rẹ̀ dùn sí mi.
20 OLUWA ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ ni ó ṣe pín mi lérè.
21 Nítorí tí mo ti pa ọ̀nà OLUWA mọ́,n kò ṣe ibi nípa yíyà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi.
22 Nítorí pé gbogbo òfin rẹ̀ ni mo tẹ̀lé,n kò sì yà kúrò ninu ìlànà rẹ̀.
23 Mo wà ní àìlẹ́bi níwájú rẹ̀,mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀.
24 Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;ati gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ lójú rẹ̀.
25 Ò máa dúró ti àwọn tí ó dúró tì ọ́,ò sì máa ṣe àṣepé fún àwọn tí ó pé;
26 mímọ́ ni ọ́ sí àwọn tí ọkàn wọn mọ́,ṣugbọn àwọn alárèékérekè ni o fi ọgbọ́n tayọ.
27 Nítorí tí o máa ń gba àwọn onírẹ̀lẹ̀ là,ṣugbọn o máa ń rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀.
28 Nítorí ìwọ ni o mú kí àtùpà mi máa tàn,OLUWA, Ọlọrun mi ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn mi.
29 Pẹlu ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, mo lè run ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun,àní, pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun mi, mo lè fo odi ìlú.
30 Ní ti Ọlọrun, ọ̀nà rẹ̀ pé,pípé ni ọ̀rọ̀ OLUWA;òun sì ni ààbò fún gbogbo àwọn tí ó sá di í.
31 Ta tún ni Ọlọrun, bíkòṣe OLUWA?Àbí, ta ni àpáta, àfi Ọlọrun wa?
32 Ọlọrun tí ó gbé agbára wọ̀ mí,tí ó sì mú ọ̀nà mi pé.
33 Ó fi eré sí mi lẹ́sẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín,ó sì fún mi ní ààbò ní ibi ìsásí.
34 Ó kọ́ mi ní ogun jíjàtóbẹ́ẹ̀ tí mo fi lè fa ọrun idẹ.
35 O ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ,ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó gbé mi ró,ìrànlọ́wọ́ rẹ sì ni ó sọ mí di ẹni ńlá.
36 O la ọ̀nà tí ó gbòòrò fún mi,n kò sì fi ẹsẹ̀ rọ́.
37 Mo lé àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ mi sì tẹ̀ wọ́n,n kò bojú wẹ̀yìn títí a fi pa wọ́n run.
38 Mo ṣá wọn lọ́gbẹ́, wọn kò lè dìde,wọ́n ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
39 O gbé agbára ogun wọ̀ mí;o sì mú àwọn tí ó dìde sí mi wólẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ mi.
40 O mú kí àwọn ọ̀tá mi máa sá níwájú mi,mo sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
41 Wọ́n kígbe pé, “Ẹ gbà wá o!”Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n,wọ́n ké pe OLUWA, ṣugbọn kò dá wọn lóhùn.
42 Mo lọ̀ wọ́n lúbúlúbú bí eruku tí afẹ́fẹ́ ń gbá lọ,mo dà wọ́n nù bí ẹni da omi ẹrẹ̀ nù.
43 O gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan,o fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè;àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò mọ̀ rí sì ń sìn mí.
44 Bí wọ́n bá ti gbúròó mi ni wọ́n ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu;àwọn àjèjì ń fi ìbẹ̀rùbojo tẹríba, wọ́n ń wá ojurere mi.
45 Àyà pá àwọn àlejò,wọ́n sì fi ìbẹ̀rùbojo sá jáde kúrò ní ibi tí wọ́n sápamọ́ sí.
46 OLUWA wà láàyè! Ẹni ìyìn ni àpáta mi!Ẹni àgbéga ni Ọlọrun ìgbàlà mi!
47 Ọlọrun tí ó ń gbẹ̀san fún mi,tí ó sì ń tẹ orí àwọn eniyan ba fún mi;
48 Ọlọrun tí ó gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;tí ó sì gbé mi ga ju àwọn abínú-ẹni lọ;ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ipá tí ó dìde sí mi.
49 Nítorí náà ni èmi ó ṣe máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, OLUWA,èmi ó sì máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.
50 Ó fi ìṣẹ́gun ńlá fún ọba rẹ̀,ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ han ẹni àmì òróró rẹ̀,àní Dafidi ati ìrandíran rẹ̀ títí lae.