1 Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,fi tinútinú yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.
2 Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,má sì ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀,
3 ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn;
4 ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn,tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé.
5 Ẹni tí ó ń fi ohun dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn,tí ó fi ń sọ agbára ìgbà èwe rẹ dọ̀tun bíi ti idì.
6 OLUWA a máa dáni lárea sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo fún gbogboàwọn tí a ni lára.
7 Ó fi ọ̀nà rẹ̀ han Mose,ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ han àwọn ọmọ Israẹli.
8 Aláàánú ati olóore ni OLUWA,kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀.
9 Kì í fi ìgbà gbogbo báni wí,bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ̀ kì í pẹ́ títí ayé.
10 Kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa,bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa bí àìdára wa.
11 Nítorí bí ọ̀run ti jìnnà sí ilẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣe tóbi tósí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
12 Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn,bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.
13 Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọntí ó bá bẹ̀rù rẹ̀.
14 Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa;ó ranti pé erùpẹ̀ ni wá.
15 Ọjọ́ ayé ọmọ eniyan dàbí ti koríko,eniyan a sì máa gbilẹ̀ bí òdòdó inú igbó;
16 ṣugbọn bí afẹ́fẹ́ bá ti fẹ́ kọjá lórí rẹ̀,á rẹ̀ dànù,ààyè rẹ̀ kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́.
17 Ṣugbọn títí ayé ni ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀,sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,òdodo rẹ̀ wà lára arọmọdọmọ wọn.
18 Ó wà lára àwọn tí ó ń pa majẹmu rẹ̀ mọ́,tí wọn sì ń ranti láti pa òfin rẹ̀ mọ́.
19 OLUWA ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run,ó sì jọba lórí ohun gbogbo.
20 Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,ẹ̀yin alágbára tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀,tí ẹ sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
21 Ẹ yin OLUWA gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀,ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
22 Ẹ yin OLUWA, gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,níbi gbogbo ninu ìjọba rẹ̀.Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi.