Orin Dafidi 88 BM

Adura nígbà ìpọ́njú

1 OLUWA, Ọlọrun, Olùgbàlà mi, mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ ní ọ̀sán;mo ké níwájú rẹ ní òru.

2 Jẹ́ kí adura mi dé ọ̀dọ̀ rẹ;tẹ́tí sí igbe mi.

3 Nítorí pé ọkàn mi kún fún ìyọnu;mo sì súnmọ́ isà òkú.

4 Mo dàbí àwọn tí ó ń wọ ibojì lọ;mo dà bí ẹni tí kò lágbára mọ.

5 N kò yàtọ̀ sí ẹni tí a pa tì sí apá kan láàrin àwọn òkú,mo dàbí ẹni tí a pa, tí ó sùn ninu ibojì,bí àwọn tí ìwọ kò ranti mọ́,nítorí pé wọ́n ti kúrò lábẹ́ ìtọ́jú rẹ.

6 O ti fi mí sinu isà òkú tí ó jìn pupọ,ninu òkùnkùn, àní ninu ọ̀gbun.

7 Ọwọ́ ibinu rẹ wúwo lára mi,ìgbì ìrúnú rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀.

8 O ti mú kí àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi fi mí sílẹ̀;mo sì ti di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn:mo wà ninu àhámọ́, n kò sì lè jáde;

9 ojú mi ti di bàìbàì nítorí ìbànújẹ́.Lojoojumọ ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA;tí mò ń tẹ́wọ́ adura sí ọ.

10 Ṣé òkú ni o óo ṣe iṣẹ́ ìyanu hàn?Ṣé àwọn òkú lè dìde kí wọ́n máa yìn ọ́?

11 Ṣé a lè sọ̀rọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ninu ibojì?Àbí ẹnìkan lè sọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ ninu ìparun?

12 Ṣé a lè rí iṣẹ́ ìyanu rẹ ninu òkùnkùn ikú?Àbí ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ wà ní ilẹ̀ àwọn tí a ti gbàgbé?

13 Ṣugbọn OLUWA, èmi ń ké pè ọ́;ní òwúrọ̀ n óo gbadura sí ọ.

14 OLUWA, kí ló dé tí o fi ta mí nù?Kí ló dé tí o fi ojú pamọ́ fún mi?

15 Láti ìgbà èwe mi ni a tí ń jẹ mí níyà,tí mo sì fẹ́rẹ̀ kú,mo ti rí ìjẹníyà rẹ tí ó bani lẹ́rù;agara sì ti dá mi.

16 Ìrúnú rẹ bò mí mọ́lẹ̀;ẹ̀rù rẹ sì bà mí dójú ikú.

17 Wọ́n yí mi ká tọ̀sán-tòru bí ìṣàn omi ńlá;wọ́n ká mi mọ́ patapata.

18 O ti mú kí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi ati àwọn alábàárìn mi kọ̀ mí sílẹ̀;òkùnkùn nìkan ni ó yí mi ká níbi gbogbo.