Orin Dafidi 34 BM

Ẹ yin Ọlọrun nítorí Oore Rẹ̀

1 N óo máa yin OLUWA ní gbogbo ìgbà;ìyìn rẹ̀ yóo máa wà ní ẹnu mi nígbà gbogbo.

2 OLUWA ni èmi óo máa fi yangàn;kí inú àwọn olùpọ́njú máa dùn nígbà tí wọ́n bá gbọ́.

3 Ẹ bá mi gbé OLUWA ga,ẹ jẹ́ kí á jùmọ̀ gbé orúkọ rẹ̀ lékè!

4 Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn,ó sì gbà mí lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ń bà mí lẹ́rù.

5 Wọ́n gbójú sókè sí OLUWA, wọ́n láyọ̀;ojú kò sì tì wọ́n.

6 Olùpọ́njú ké pe OLUWA, OLUWA gbọ́ ohùn rẹ̀,ó sì gbà á ninu gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.

7 Angẹli OLUWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká,a sì máa gbà wọ́n.

8 Tọ́ ọ wò, kí o sì rí i pé rere ni OLUWA!Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá sá di í!

9 Ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ̀yin eniyan mímọ́ rẹ̀,nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀!

10 Àwọn ọmọ kinniun a máa ṣe aláìní,ebi a sì máa pa wọ́n;ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá ń wá OLUWAkò ní ṣe aláìní ohun rere kankan.

11 Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ tẹ́tí sí mi,n óo kọ yín ní ìbẹ̀rù OLUWA.

12 Ta ni ń fẹ́ ìyè ninu yín,tí ń fẹ́ ẹ̀mí gígùn,tí ó fẹ́ pẹ́ láyé?

13 Ẹ ṣọ́ ẹnu yín, ẹ má sọ̀rọ̀ burúkú,ẹ má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu yín jáde.

14 Ẹ yàgò fún ibi, rere ni kí ẹ máa ṣe;ẹ máa wá alaafia, kí ẹ sì máa lépa rẹ̀.

15 OLUWA ń ṣọ́ àwọn olódodo,Ó sì ń dẹ etí sí igbe wọn.

16 OLUWA fojú sí àwọn aṣebi lára,láti pa wọ́n rẹ́, kí á má sì ṣe ranti wọn mọ́ lórí ilẹ̀ ayé.

17 Nígbà tí olódodo bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA a máa gbọ́,a sì máa gbà wọ́n kúrò ninu gbogbo ìyọnu wọn.

18 OLUWA wà nítòsí àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́,a sì máa gba àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn là.

19 Ìpọ́njú olódodo a máa pọ̀;ṣugbọn OLUWA a máa kó o yọ ninu gbogbo wọn.

20 A máa pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́;kì í jẹ́ kí ọ̀kankan fọ́ ninu wọn.

21 Ibi ni yóo pa eniyan burúkú;a óo sì dá àwọn tí ó kórìíra olódodo lẹ́bi.

22 OLUWA ra ẹ̀mí àwọn iranṣẹ rẹ̀ pada;ẹnikẹ́ni tí ó bá sá di í kò ní jẹ̀bi.