Orin Dafidi 119 BM

Òfin OLUWA

1 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ìgbé ayé wọn kò lábàwọ́n,àní àwọn tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA.

2 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́,tí wọn ń fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

3 Àwọn tí wọn kò dẹ́ṣẹ̀,ṣugbọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

4 O ti pàṣẹ pé kí á fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́,

5 Ìbá ti dára tótí mo bá lè dúró ṣinṣin ninu ìlànà rẹ!

6 Òun ni ojú kò fi ní tì mí,nítorí pé òfin rẹ ni mò ń tẹ̀lé.

7 N óo yìn ọ́ pẹlu inú mímọ́,bí mo ṣe ń kọ́ ìlànà òdodo rẹ.

8 N óo máa pa òfin rẹ mọ́,má kọ̀ mí sílẹ̀ patapata.

Pípa Òfin OLUWA mọ́

9 Báwo ni ọdọmọkunrin ṣe lè mú kí ọ̀nà rẹ̀ mọ́?Nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ ni.

10 Tọkàntọkàn ni mo fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ,má jẹ́ kí n ṣìnà kúrò ninu òfin rẹ.

11 Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn,kí n má baà ṣẹ̀ ọ́.

12 Ìyìn ni fún ọ, OLUWA,kọ́ mi ní ìlànà rẹ!

13 Mo fi ẹnu mi kéde gbogbo àṣẹ tí o pa.

14 Mo láyọ̀ ninu pípa òfin rẹ mọ́,bí ẹni tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.

15 N óo máa ṣe àṣàrò ninu òfin rẹ,n óo sì kọjú sí ọ̀nà rẹ.

16 N óo láyọ̀ ninu àwọn ìlànà rẹ,n kò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.

Ayọ̀ ninu Òfin OLUWA

17 Ṣe ọpọlọpọ oore fún èmi iranṣẹ rẹ,kí n lè wà láàyè,kí n sì máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.

18 Là mí lójú, kí n lè rí àwọn nǹkan ìyanutí ó wà ninu òfin rẹ.

19 Àlejò ni mí láyé,má fi òfin rẹ pamọ́ fún mi.

20 Òùngbẹ títẹ̀lé òfin rẹ ń gbẹ ọkàn mi, nígbà gbogbo.

21 O bá àwọn onigbeeraga wí, àwọn ẹni ègún,tí wọn kò pa òfin rẹ mọ́.

22 Mú ẹ̀gàn ati àbùkù wọn kúrò lára mi,nítorí pé mo ti pa òfin rẹ mọ́.

23 Bí àwọn ìjòyè tilẹ̀ gbìmọ̀ràn ọ̀tẹ̀ nítorí mi,sibẹ, èmi iranṣẹ rẹ yóo ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ.

24 Àwọn òfin rẹ ni dídùn inú mi,àwọn ni olùdámọ̀ràn mi.

Ìpinnu láti Pa Òfin OLUWA mọ́

25 Mo di ẹni ilẹ̀,sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.

26 Nígbà tí mo jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe mi, o dá mi lóhùn;kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

27 La òfin rẹ yé mi,n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí iṣẹ́ ìyanu rẹ.

28 Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi nítorí ìbànújẹ́,mú mi lọ́kàn le gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.

29 Mú ìwà èké jìnnà sí mi,kí o sì fi oore ọ̀fẹ́ kọ́ mi ní òfin rẹ.

30 Mo ti yan ọ̀nà òtítọ́,mo ti fi ọkàn sí òfin rẹ.

31 Mo pa òfin rẹ mọ́, OLUWA,má jẹ́ kí ojú ó tì mí.

32 N óo yára láti pa òfin rẹ mọ́,nígbà tí o bá mú òye mi jinlẹ̀ sí i.

Adura fún Òye

33 OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ,n óo sì pa wọ́n mọ́ dé òpin.

34 Là mí lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́,kí n sì máa fi tọkàntọkàn pa wọ́n mọ́.

35 Tọ́ mi sí ọ̀nà nípa òfin rẹ,nítorí pé mo láyọ̀ ninu rẹ̀.

36 Mú kí ọkàn mi fà sí òfin rẹ,kí ó má fà sí ọrọ̀ ayé.

37 Yí ojú mi kúrò ninu wíwo nǹkan asán,sọ mí di alààyè ní ọ̀nà rẹ.

38 Mú ìlérí rẹ ṣẹ fún iranṣẹ rẹ,àní, ìlérí tí o ṣe fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ.

39 Mú ẹ̀gàn tí ń bà mí lẹ́rù kúrò,nítorí pé ìlànà rẹ dára.

40 Wò ó, ọkàn mi fà sí ati máa tẹ̀lé ìlànà rẹ,sọ mí di alààyè nítorí òdodo rẹ!

Gbígbẹ́kẹ̀lé ninu Òfin OLUWA

41 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn mí, OLÚWA,kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

42 Nígbà náà ni n óo lè dá àwọn tí ń gàn mí lóhùn,nítorí mo gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.

43 Má gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ lẹ́nu mi rárá,nítorí ìrètí mi ń bẹ ninu ìlànà rẹ.

44 N óo máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo, lae ati laelae.

45 N óo máa rìn fàlàlà,nítorí pé mo tẹ̀lé ìlànà rẹ.

46 N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba,ojú kò sì ní tì mí.

47 Mo láyọ̀ ninu òfin rẹ,nítorí tí mo fẹ́ràn rẹ̀.

48 Mo bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ tí mo fẹ́ràn,n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ.

Igbẹkẹle ninu Òfin OLUWA

49 Ranti ọ̀rọ̀ tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ,èyí tí ó fún mi ní ìrètí.

50 Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé:ìlérí rẹ mú mi wà láàyè.

51 Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi,ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀.

52 Mo ranti òfin rẹ àtijọ́,OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀.

53 Inú mi á máa ru,nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú,tí wọn ń rú òfin rẹ.

54 Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ,lákòókò ìrìn àjò mi láyé.

55 Mo ranti orúkọ rẹ lóru;OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́:

56 Èyí ni ìṣe mi:Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́.

Ìfọkànsí Òfin OLUWA

57 OLUWA, ìwọ nìkan ni mo ní;mo ṣe ìlérí láti pa òfin rẹ mọ́.

58 Tọkàntọkàn ni mò ń wá ojurere rẹ,ṣe mí lóore gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

59 Nígbà tí mo ronú nípa ìṣe mi,mo yipada sí ìlànà rẹ;

60 mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́.

61 Bí okùn àwọn eniyan burúkú tilẹ̀ wé mọ́ mi,n kò ní gbàgbé òfin rẹ.

62 Mo dìde lọ́gànjọ́ láti yìn ọ́,nítorí ìlànà òdodo rẹ.

63 Ọ̀rẹ́ gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ ni mí,àní, àwọn tí wọn ń pa òfin rẹ mọ́.

64 OLUWA, ayé kún fún ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

Iyebíye ni Òfin OLUWA

65 OLUWA, o ti ṣeun fún èmi iranṣẹ rẹ,gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

66 Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé,nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ.

67 Kí o tó jẹ mí níyà, mo yapa kúrò ninu òfin rẹ;ṣugbọn nisinsinyii, mò ń mú àṣẹ rẹ ṣẹ.

68 OLUWA rere ni ọ́, rere ni o sì ń ṣe;kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

69 Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀,ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́.

70 Ọkàn wọn ti yigbì,ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ.

71 Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani,ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ.

72 Òfin rẹ níye lórí fún mi,ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ.

Òdodo ni Òfin OLUWA

73 Ìwọ ni o mọ mí, ìwọ ni o dá mi,fún mi ní òye kí n lè kọ́ òfin rẹ.

74 Inú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yóo máa dùnnígbà tí wọ́n bá rí mi,nítorí pé mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.

75 OLUWA, mo mọ̀ pé ìdájọ́ rẹ tọ̀nà,ati pé lórí ẹ̀tọ́ ni o pọ́n mi lójú.

76 Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ máa tù mí ninu,gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe fún èmi, iranṣẹ rẹ.

77 Ṣàánú mi, kí n lè wà láàyè,nítorí pé òfin rẹ ni ìdùnnú mi.

78 Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn onigbeeraga,nítorí wọ́n ṣe àrékérekè sí mi láìnídìí;ní tèmi, n óo máa ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ.

79 Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ tọ̀ mí wá,kí wọ́n lè mọ òfin rẹ.

80 Níti pípa òfin rẹ mọ́, jẹ́ kí n pé,kí ojú má baà tì mí.

Adura Ìdáǹdè

81 Mo wá ìgbàlà rẹ títí, àárẹ̀ mú ọkàn mi;ṣugbọn mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.

82 Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,níbi tí mo tí ń retí ìmúṣẹ ìlérí rẹ.Mo ní, “Nígbà wo ni o óo tù mí ninu?”

83 Mo dàbí agbè ọtí tí ó ti di àlòpatì,sibẹ, n kò gbàgbé ìlànà rẹ.

84 Èmi iranṣẹ rẹ yóo ti dúró pẹ́ tó?Nígbà wo ni ìwọ óo dájọ́ fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi?

85 Àwọn onigbeeraga ti gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,àní, àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́.

86 Gbogbo òfin rẹ ló dájú;ràn mí lọ́wọ́, nítorí wọ́n ń fi ìwà èké ṣe inúnibíni mi.

87 Wọ́n fẹ́rẹ̀ pa mí run láyé,ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀.

88 Dá ẹ̀mí mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,kí n lè máa mú gbogbo àṣẹ rẹ ṣẹ.

Igbagbọ ninu Òfin OLUWA

89 OLUWA, títí lae ni ọ̀rọ̀ rẹ fìdí múlẹ̀ lọ́run.

90 Òtítọ́ rẹ wà láti ìrandíran;o ti fi ìdí ayé múlẹ̀, ó sì dúró.

91 Ohun gbogbo wà gẹ́gẹ́ bí ìlànà rẹ, títí di òní,nítorí pé iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn.

92 Bí kò bá jẹ́ pé òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi,ǹ bá ti ṣègbé ninu ìpọ́njú.

93 Lae, n kò ní gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ,nítorí pé, nípasẹ̀ wọn ni o fi mú mi wà láyé.

94 Ìwọ ni o ni mí, gbà mí;nítorí pé mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.

95 Àwọn eniyan burúkú ba dè mí,wọ́n fẹ́ pa mí run,ṣugbọn mò ń ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ.

96 Mo ti rí i pé kò sí ohun tí ó lè pé tán,àfi òfin rẹ nìkan ni kò lópin.

Ìfẹ́ sí Òfin OLUWA

97 Mo fẹ́ràn òfin rẹ lọpọlọpọ!Òun ni mo fi ń ṣe àṣàrò tọ̀sán-tòru.

98 Ìlànà rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,nítorí pé òun ni ó ń darí mi nígbà gbogbo.

99 Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ,nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò.

100 Òye mi ju ti àwọn àgbà lọ,nítorí pé mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.

101 N kò rin ọ̀nà ibi kankan,kí n lè pa òfin rẹ mọ́.

102 N kò yapa kúrò ninu òfin rẹ,nítorí pé o ti kọ́ mi.

103 Ọ̀rọ̀ rẹ dùn mọ́ mi pupọ,ó dùn ju oyin lọ.

104 Nípa ẹ̀kọ́ rẹ ni mo fi ní òye,nítorí náà mo kórìíra gbogbo ìwà èké.

Ìmọ́lẹ̀ láti Inú Òfin OLUWA

105 Ọ̀rọ̀ rẹ ni àtùpà fún ẹsẹ̀ mi,òun ni ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà mi.

106 Mo ti búra, n óo sì mú un ṣẹ,pé n óo máa pa òfin òdodo rẹ mọ́.

107 Ojú ń pọ́n mi lọpọlọpọ,sọ mí di alààyè, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

108 Gba ẹbọ ìyìn àtọkànwá mi, OLUWA,kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

109 Ayé mi wà ninu ewu nígbà gbogbo,ṣugbọn n kò gbàgbé òfin rẹ.

110 Àwọn eniyan burúkú ti dẹ okùn sílẹ̀ dè mí,ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀.

111 Ìlànà rẹ ni ogún mi títí lae,nítorí pé òun ni ayọ̀ mi.

112 Mo ti pinnu láti máa tẹ̀lé ìlànà rẹ nígbà gbogbo,àní, títí dé òpin.

Ààbò ninu Òfin OLUWA

113 Mo kórìíra àwọn oníyèméjì,ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ.

114 Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi ati asà mi,mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.

115 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi,kí n lè pa òfin Ọlọrun mi mọ́.

116 Gbé mi ró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, kí n lè wà láàyè,má sì dójú ìrètí mi tì mí.

117 Gbé mi ró, kí n lè wà láìléwu,kí n lè máa ka ìlànà rẹ sí nígbà gbogbo.

118 O ti kọ gbogbo àwọn tí ó yapa kúrò ninu ìlànà rẹ sílẹ̀,nítorí pé asán ni gbogbo ẹ̀tàn wọn.

119 O ti pa àwọn eniyan burúkú tì, bí ìdàrọ́ irin,nítorí náà ni mo ṣe fẹ́ràn ìlànà rẹ.

120 Mo wárìrì nítorí pé mo bẹ̀rù rẹ,mo sì bẹ̀rù ìdájọ́ rẹ.

Pípa Òfin OLUWA mọ́

121 Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́ tí ó sì yẹ,má fi mí sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń ni mí lára.

122 Ṣe ìlérí ìrànlọ́wọ́ fún ire èmi iranṣẹ rẹ,má sì jẹ́ kí àwọn onigbeeraga ni mí lára.

123 Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,níbi tí mo tí ń retí ìgbàlà rẹ,ati ìmúṣẹ ìlérí òdodo rẹ.

124 Ṣe sí èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

125 Iranṣẹ rẹ ni mí,fún mi lóye, kí n lè mọ ìlànà rẹ.

126 OLUWA, ó tó àkókò fún ọ láti ṣe nǹkankan,nítorí àwọn eniyan ń rú òfin rẹ.

127 Nítorí náà ni èmi ṣe fẹ́ràn òfin rẹju wúrà lọ; àní, ju ojúlówó wúrà.

128 Nítorí náà, èmi ń tẹ̀lé gbogbo ẹ̀kọ́ rẹ,mo sì kórìíra gbogbo ọ̀nà èké.

Ìfẹ́ láti Pa Òfin OLUWA Mọ́

129 Òfin rẹ dára,nítorí náà ni mo ṣe ń pa wọ́n mọ́.

130 Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ a máa fúnni ní ìmọ́lẹ̀,a sì máa fi òye fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.

131 Mo la ẹnu, mò ń mí hẹlẹ,nítorí pé mò ń lépa òfin rẹ.

132 Kọjú sí mi kí o ṣe mí lóorebí o ti máa ń ṣesí àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ.

133 Mú ẹsẹ̀ mi dúró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ,má sì jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ kankan jọba lórí mi.

134 Gbà mí lọ́wọ́ ìnilára àwọn eniyan,kí n lè máa tẹ̀lé ìlànà rẹ.

135 Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí ara èmi iranṣẹ rẹ;kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

136 Omijé ń dà lójú mi pòròpòrò,nítorí pé àwọn eniyan kò pa òfin rẹ mọ́.

Títọ́ Òfin OLUWA

137 Olódodo ni ọ́, OLUWA,ìdájọ́ rẹ sì tọ́.

138 Òdodo ni o fi pa àṣẹ rẹ,òtítọ́ patapata ni.

139 Mò ń tara gidigidi,nítorí pé àwọn ọ̀tá mi gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.

140 A ti yẹ ọ̀rọ̀ rẹ wò fínnífínní, ó dúró ṣinṣin,mo sì fẹ́ràn rẹ̀.

141 Bí mo tilẹ̀ kéré, tí ayé sì kẹ́gàn mi,sibẹ n kò gbàgbé ìlànà rẹ.

142 Òdodo rẹ wà títí lae,òtítọ́ sì ni òfin rẹ.

143 Ìyọnu ati ìpayà dé bá mi,ṣugbọn mo láyọ̀ ninu òfin rẹ.

144 Òdodo ni ìlànà rẹ títí lae,fún mi ní òye kí n lè wà láàyè.

Adura Ìdáǹdè

145 Tọkàntọkàn ni mo fi ń ké pè ọ́,OLUWA, dá mi lóhùn;n óo sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ.

146 Mo ké pè ọ́; gbà mí,n óo sì máa mú àṣẹ rẹ ṣẹ.

147 Mo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́;mò ń retí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ.

148 N kò fi ojú ba oorun ní gbogbo òru,kí n lè máa ṣe àṣàrò lórí ọ̀rọ̀ rẹ.

149 Gbóhùn mi nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,OLÚWA, dá mi sí nítorí òtítọ́ rẹ.

150 Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi súnmọ́ tòsí;wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.

151 Ṣugbọn ìwọ wà nítòsí, OLUWA,òtítọ́ sì ni gbogbo òfin rẹ.

152 Ó pẹ́ tí mo ti kọ́ ninu ìlànà rẹ,pé o ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae.

Ẹ̀bẹ̀ fún Ìrànlọ́wọ́

153 Wo ìpọ́njú mi, kí o gbà mí,nítorí n kò gbàgbé òfin rẹ.

154 Gba ẹjọ́ mi rò, kí o sì gbà mí,sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

155 Ìgbàlà jìnnà sí àwọn eniyan burúkú,nítorí wọn kò wá ìlànà rẹ.

156 Àánú rẹ pọ̀, OLUWA,sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ rẹ.

157 Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi ati àwọn ọ̀tá mi pọ̀,ṣugbọn n kò yapa kúrò ninu ìlànà rẹ.

158 Mò ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀ pẹlu ìríra,nítorí wọn kì í pa òfin rẹ mọ́.

159 Wo bí mo ti fẹ́ ẹ̀kọ́ rẹ tó!Dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

160 Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ,gbogbo òfin òdodo rẹ ni yóo máa wà títí lae.

Fífi Ara Ẹni fún Òfin OLUWA

161 Àwọn ìjòyè ń ṣe inúnibíni mi láìnídìí,ṣugbọn mo bẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ tọkàntọkàn.

162 Mo láyọ̀ ninu ọ̀rọ̀ rẹ,bí ẹni pé mo ní ọpọlọpọ ìkógun.

163 Mo kórìíra èké ṣíṣe, ara mi kọ̀ ọ́,ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ.

164 Nígbà meje lojoojumọ ni mò ń yìn ọ́nítorí òfin òdodo rẹ.

165 Alaafia ńláńlá ń bẹ fún àwọn tí ó fẹ́ràn òfin rẹ,kò sí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.

166 Mò ń retí ìgbàlà rẹ, OLUWA,mo sì ń pa àwọn òfin rẹ mọ́.

167 Mò ń pa àṣẹ rẹ mọ́,mo fẹ́ràn wọn gidigidi.

168 Mo gba ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ;gbogbo ìṣe mi ni ò ń rí.

Adura Ìrànlọ́wọ́

169 Jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ, OLUWA,fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

170 Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi dé iwájú rẹ,kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

171 Ẹnu mi yóo kún fún ìyìn rẹ,pé o ti kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

172 N óo máa fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe orin kọ,nítorí pé gbogbo òfin rẹ ni ó tọ̀nà.

173 Múra láti ràn mí lọ́wọ́,nítorí pé mo ti gba ẹ̀kọ́ rẹ.

174 Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, OLUWA;òfin rẹ sì ni inú dídùn mi.

175 Dá mi sí kí n lè máa yìn ọ́,sì jẹ́ kí òfin rẹ ràn mí lọ́wọ́.

176 Mo ti ṣìnà bí aguntan tó sọnù;wá èmi, iranṣẹ rẹ, rí,nítorí pé n kò gbàgbé òfin rẹ.