1 OLUWA, ìwọ ni o ti jẹ́ ibi ààbò wa láti ìrandíran.
2 Kí o tó dá àwọn òkè,ati kí o tó dá ilẹ̀ ati ayé,láti ayérayé, ìwọ ni Ọlọrun.
3 O sọ eniyan di erùpẹ̀ pada,o sì wí pé, “Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ eniyan.”
4 Nítorí pé lójú rẹ, ẹgbẹrun ọdún dàbí àná,tabi bí ìṣọ́ kan ní òru.
5 Ìwọ a máa gbá ọmọ eniyan dànù; wọ́n dàbí àlá,bíi koríko tí ó tutù ní òwúrọ̀;
6 ní òwúrọ̀ á máa gbilẹ̀, á sì máa jí pérépéré;ní ìrọ̀lẹ́ á sá, á sì rọ.
7 Ibinu rẹ pa wá run;ìrúnú rẹ sì bò wá mọ́lẹ̀.
8 O ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa kalẹ̀ ní iwájú rẹ;àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wa sì hàn kedere ninu ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.
9 Nítorí ọjọ́ ayé wa ń kọjá lọ ninu ibinu rẹ;ayé wa sì ń dópin bí ẹni mí kanlẹ̀.
10 Aadọrin ọdún ni ọjọ́ ayé wa;pẹlu ipá a lè tó ọgọrin;sibẹ gbogbo rẹ̀ jẹ́ kìkì làálàá ati ìyọnu;kíá, ayé wa á ti dópin, ẹ̀mí wa á sì fò lọ.
11 Ta ló mọ agbára ibinu rẹ?Ta ló sì mọ̀ pé bí ẹ̀rù rẹ ti tó bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ rí?
12 Nítorí náà kọ́ wa láti máa ka iye ọjọ́ orí wa,kí á lè kọ́gbọ́n.
13 Yipada sí wa, OLUWA; yóo ti pẹ́ tó tí o óo máa bínú sí wa?Ṣàánú àwa iranṣẹ rẹ.
14 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀,kí á lè máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùnní gbogbo ọjọ́ ayé wa.
15 Mú inú wa dùn fún iye ọjọ́ tí oti fi pọ́n wa lójú,ati fún iye ọdún tí ojú wa ti fi rí ibi.
16 Jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ,kí agbára rẹ tí ó lógo sì hàn sí àwọn ọmọ wọn.
17 Jẹ́ kí ojurere OLUWA Ọlọrun wa wà lára wa,fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀,jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wa fi ìdí múlẹ̀.