1 OLUWA, o fi ojurere wo ilẹ̀ rẹ;o dá ire Jakọbu pada.
2 O dárí àìdára àwọn eniyan rẹ jì wọ́n;o sì bo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
3 O mú ìrúnú rẹ kúrò;o dáwọ́ ibinu gbígbóná rẹ dúró.
4 Tún mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun Olùgbàlà wa;dáwọ́ inú tí ń bí ọ sí wa dúró.
5 Ṣé o óo máa bínú sí wa títí lae ni?Ṣé ibinu rẹ yóo máa tẹ̀síwájú láti ìran dé ìran ni?
6 Ṣé o ò ní tún sọ wá jí ni,kí àwọn eniyan rẹ lè máa yọ̀ ninu rẹ?
7 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn wá, OLUWA;kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.
8 Jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí Ọlọrun, OLUWA yóo wí,nítorí pé ọ̀rọ̀ alaafia ni yóo sọ fún àwọn eniyan rẹ̀,àní, àwọn olùfọkànsìn rẹ̀,ṣugbọn kí wọn má yipada sí ìwà òmùgọ̀.
9 Nítòótọ́, ìgbàlà rẹ̀ wà nítòsí fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;kí ògo rẹ̀ lè wà ní ilẹ̀ wa.
10 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ yóo pàdé;òdodo ati alaafia yóo dì mọ́ ara wọn.
11 Òtítọ́ yóo rú jáde láti inú ilẹ̀;òdodo yóo sì bojú wolẹ̀ láti ojú ọ̀run.
12 Dájúdájú, OLUWA yóo fúnni ní ohun tí ó dára;ilẹ̀ wa yóo sì mú èso jáde lọpọlọpọ.
13 Òdodo yóo máa rìn lọ níwájú rẹ̀,yóo sì sọ ipasẹ̀ rẹ̀ di ọ̀nà.