1 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA, gbogbo ilẹ̀ ayé.
2 Ẹ fi ayọ̀ sin OLUWA.Ẹ wá siwaju rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀.
3 Ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ni Ọlọrun,òun ló dá wa, òun ló ni wá;àwa ni eniyan rẹ̀,àwa sì ni agbo aguntan rẹ̀.
4 Ẹ wọ ẹnubodè rẹ̀ tẹ̀yin tọpẹ́,kí ẹ sì wọ inú àgbàlá rẹ̀ tẹ̀yin tìyìn.Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,kí ẹ sì máa yin orúkọ rẹ̀.
5 Nítorí OLUWA ṣeun;ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae,òtítọ́ rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.