1 Tẹ́tí sí adura mi, Ọlọrun,má sì fara pamọ́ nígbà tí mo bá ń bẹ̀bẹ̀.
2 Fetí sí mi, kí o sì dá mi lóhùn;ìṣòro ti borí mi.
3 Ìhàlẹ̀ ọ̀tá bà mí ninu jẹ́,nítorí ìnilára àwọn eniyan burúkú;wọ́n kó ìyọnu bá mi,wọ́n ń bínú mi, inú wọn sì dùn láti máa bá mi ṣọ̀tá.
4 Ọkàn mi wà ninu ìrora,ìpayà ikú ti dé bá mi.
5 Ẹ̀rù ati ìwárìrì dà bò mí,ìpayà sì bò mí mọ́lẹ̀.
6 Mo ní, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!Ǹ bá fò lọ, ǹ bá lọ sinmi.
7 Áà! Ǹ bá lọ jìnnà réré,kí n lọ máa gbé inú ijù;
8 ǹ bá yára lọ wá ibi ààbòkúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́ líle ati ìjì.”
9 Da èrò wọn rú, OLUWA,kí o sì dà wọ́n lédè rú;nítorí ìwà ipá ati asọ̀ pọ̀ ninu ìlú.
10 Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń yí orí odi rẹ̀ ká;ìwà ìkà ati ìyọnu ni ó sì pọ̀ ninu rẹ̀.
11 Ìparun wà ninu rẹ̀;ìnilára ati ìwà èrú kò sì kúrò láàrin ìgboro rẹ̀.
12 Bí ó bá ṣe pé ọ̀tá ní ń gàn mí,ǹ bá lè fara dà á.Bí ó bá ṣe pé ẹni tí ó kórìíra mi ní ń gbéraga sí mi,ǹ bá fara pamọ́ fún un.
13 Ṣugbọn ìwọ ni; ìwọ tí o jẹ́ irọ̀ mi,alábàárìn mi, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́.
14 À ti jọ máa sọ ọ̀rọ̀ dídùndídùn pọ̀ rí;a sì ti jọ rìn ní ìrẹ́pọ̀ ninu ilé Ọlọrun.
15 Jẹ́ kí ikú jí àwọn ọ̀tá mi pa;kí wọ́n lọ sinu isà òkú láàyè;kí wọ́n wọ ibojì lọ pẹlu ìpayà.
16 Ṣugbọn èmi ké pe Ọlọrun;OLUWA yóo sì gbà mí.
17 Mò ń ráhùn tọ̀sán-tòru,mo sì ń kérora; OLUWA óo gbọ́ ohùn mi.
18 Yóo yọ mí láìfarapa,ninu ogun tí mò ń jà,nítorí ọ̀pọ̀ ni àwọn tí wọ́n dojú kọ mí,tí wọn ń bá mi jà.
19 Ọlọrun tí ó gúnwà láti ìgbàanì yóo gbọ́,yóo sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,nítorí pé wọn kò pa ìwà wọn dà,wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọrun.
20 Alábàárìn mi gbógun ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀,ó yẹ àdéhùn rẹ̀.
21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn ju oyin lọ,bẹ́ẹ̀ sì ni ìjà ni ó wà lọ́kàn rẹ̀;ọ̀rọ̀ rẹ̀ tutù ju omi àmù lọ,ṣugbọn idà aṣekúpani ni.
22 Kó gbogbo ìṣòro rẹ lé OLUWA lọ́wọ́,yóo sì gbé ọ ró;kò ní jẹ́ kí á ṣí olódodo ní ipò pada.
23 Ṣugbọn ìwọ, Ọlọrun, o óo sọ àwọn apaniati àwọn alárèékérekè, sinu kòtò ìparun;wọn kò ní lo ìdajì ọjọ́ ayé wọn.Ṣugbọn èmi óo gbẹ́kẹ̀lé ọ.