Orin Dafidi 31 BM

Adura Igbẹkẹle Ọlọrun

1 OLUWA, ìwọ ni mo sá di,má jẹ́ kí ojú tì mí lae;gbà mí, nítorí olóòótọ́ ni ọ́.

2 Dẹ etí sí mi, yára gbà mí.Jẹ́ àpáta ààbò fún mi;àní ilé ààbò tó lágbára láti gbà mí là.

3 Ìwọ ni àpáta ati ilé ààbò mi;nítorí orúkọ rẹ, máa tọ́ mi kí o sì máa fọ̀nà hàn mí.

4 Yọ mí kúrò ninu àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ dè mí,nítorí ìwọ ni ẹni ìsádi mi.

5 Ìwọ ni mo fi ẹ̀mí mi lé lọ́wọ́,o ti rà mí pada, OLUWA, Ọlọrun, olóòótọ́.

6 Mo kórìíra àwọn tí ń bọ oriṣa lásánlàsàn,ṣugbọn OLUWA ni èmi gbẹ́kẹ̀lé.

7 N óo máa yọ̀, inú mi óo sì máa dùn,nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;nítorí pé o ti rí ìpọ́njú mi,o sì mọ ìṣòro mi.

8 O ò fi mí lé ọ̀tá lọ́wọ́,o sì ti fi ẹsẹ̀ mi lé ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.

9 Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí pé mo wà ninu ìṣòro.Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì;àárẹ̀ sì mú ọkàn ati ara mi.

10 Nítorí pé ìbànújẹ́ ni mo fi ń lo ayé mi;ìmí ẹ̀dùn ni mo sì fi ń lo ọdún kan dé ekeji.Ìpọ́njú ti gba agbára mi;gbogbo egungun mi sì ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ.

11 Ẹni ẹ̀gàn ni mí láàrin gbogbo àwọn ọ̀tá mi,àwòsọkún ni mí fún àwọn aládùúgbò.Mo di àkòtagìrì fún àwọn ojúlùmọ̀ mi,àwọn tí ó rí mi lóde sì ń sá fún mi.

12 Mo di ẹni ìgbàgbé bí ẹni tí ó ti kú;mo dàbí àkúfọ́ ìkòkò.

13 Mò ń gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,bí wọ́n ti ń gbìmọ̀ pọ̀ nípa mi,tí wọ́n sì ń pète ati pa mí;wọ́n ń ṣẹ̀rù bà mí lọ́tùn-ún lósì.

14 Ṣugbọn, mo gbẹ́kẹ̀lé ọ, OLUWA,Mo ní, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.”

15 Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi,ati lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi.

16 Jẹ́ kí èmi iranṣẹ rẹ rí ojurere rẹ,gbà mí là, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

17 Má jẹ́ kí ojú tì mí, OLUWA,nítorí ìwọ ni mò ń ké pè.Jẹ́ kí ojú ti àwọn eniyan burúkú;jẹ́ kí ẹnu wọn wọ wòwò títí wọ ibojì.

18 Jẹ́ kí àwọn òpùrọ́ yadi,àní àwọn tí ń fi ìgbéraga ati ẹ̀gàn sọ̀rọ̀ àìdára nípa olódodo.

19 Háà! Ohun rere mà pọ̀ lọ́wọ́ rẹ otí o ti sọ lọ́jọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,tí o sì ti pèsè ní ìṣojú àwọn ọmọ eniyan,fún àwọn tí ó sá di ọ́.

20 O fi ìyẹ́ apá rẹ ṣíji bò wọ́n;o pa wọ́n mọ́ kúrò ninu rìkíṣí àwọn eniyan;o sì pa wọ́n mọ́ lábẹ́ ààbò rẹ,kúrò lọ́wọ́ ẹnu àwọn ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.

21 Ẹni ìyìn ni OLUWA, nítorí pé, lọ́nà ìyanu,ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn mí,nígbà tí ilẹ̀ ká mi mọ́.

22 Ẹ̀rù bà mí, mo sì sọ pé,“A lé mi jìnnà kúrò ní iwájú rẹ.”Ṣugbọn o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ minígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

23 Ẹ fẹ́ràn OLUWA, gbogbo ẹ̀yin olódodo,OLUWA a máa ṣọ́ àwọn olóòótọ́,a sì máa san àlékún ẹ̀san fún àwọn agbéraga.

24 Ẹ múra gírí, kí ẹ sì mọ́kàn le,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.