1 Nítòótọ́ Ọlọrun ṣeun fún Israẹli,ó ṣeun fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́.
2 Ṣugbọn, ní tèmi, mo fẹ́rẹ̀ yọ̀ ṣubú,ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tàsé.
3 Nítorí mò ń ṣe ìlara àwọn onigbeeraganígbà tí mo rí ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú.
4 Wọn kì í jẹ ìrora kankan,ara wọn dá pé, ó sì jọ̀lọ̀.
5 Wọn kì í ní wahala bí àwọn ẹlòmíràn;ìyọnu tíí dé bá àwọn ẹlòmíràn kì í dé ọ̀dọ̀ wọn.
6 Nítorí náà, wọn á kó ìgbéraga bọ ọrùn bí ẹ̀gbà,wọn á fi ìwà ipá bora bí aṣọ.
7 Wọ́n sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú wọn yíbò;èrò òmùgọ̀ sì kún ọkàn wọn ní àkúnwọ́sílẹ̀.
8 Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara;wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀.
9 Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun;wọn a sì máa sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé.
10 Nítorí náà, àwọn eniyan á yipada, wọn á fara mọ́ wọn,wọn á máa yìn wọ́n, láìbìkítà fún ibi tí wọn ń ṣe.
11 Wọn á máa wí pé, “Báwo ni Ọlọrun ṣe lè mọ̀?Ǹjẹ́ Ọ̀gá Ògo tilẹ̀ ní ìmọ̀?”
12 Ẹ wò ó! Ayé àwọn eniyan burúkú nìwọ̀nyí;ara dẹ̀ wọ́n nígbà gbogbo, ọrọ̀ wọn sì ń pọ̀ sí i.
13 Lásán ni gbogbo aáyan mi láti rí i pé ọkàn mi mọ́,tí mo sì yọwọ́-yọsẹ̀ ninu ibi.
14 Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni mò ń rí ìyọnu;láràárọ̀ ni à ń jẹ mí níyà.
15 Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,”n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà.
16 Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi,mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni.
17 Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ,ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn.
18 Nítòótọ́ ibi tí ń yọ̀ ni ó gbé wọn lé,ó sì mú kí wọn ṣubú sinu ìparun.
19 Wò ó bí wọn ṣe parun lọ́gán,tí ìpayà sì gbá wọn lọ patapata.
20 Wọ́n dàbí àlá tíí pòórá nígbà tí eniyan bá ta jí.OLUWA, nígbà tí o bá jí gìrì, wọn óo pòórá.
21 Nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́,tí ọ̀rọ̀ náà gbóná lára mi,
22 mo hùwà òmùgọ̀, n kò sì lóye,mo sì dàbí ẹranko lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.
23 Sibẹsibẹ nígbà gbogbo ni mo wà lọ́dọ̀ rẹ;o sì di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.
24 Ò ń fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi sọ́nà;lẹ́yìn náà, o óo sì gbà mí sinu ògo.
25 Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ?Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ.
26 Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi,ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi,ati ìpín mi títí lae.
27 Ó dájú pé àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóo ṣègbé,o óo sì pa àwọn tí ó bá ṣe alaiṣootọ sí ọ run.
28 Ní tèmi o, ó dára láti súnmọ́ Ọlọrun;mo ti fi ìwọ OLUWA Ọlọrun ṣe ààbò mi,kí n lè máa ròyìn gbogbo iṣẹ́ rẹ.