1 OLUWA, n óo máa kọrin ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ títí lae;n óo máa fi ẹnu mi kéde òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.
2 Nítorí pé, a ti fi ìdí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ múlẹ̀ títí lae;o sì ti fi ìdí òtítọ́ rẹ múlẹ̀ bí ojú ọ̀run.
3 O sọ pé, “Mo ti dá majẹmu kan pẹluẹni tí mo yàn,mo ti búra fún Dafidi, iranṣẹ mi, pé,
4 ‘N óo fi ìdí àwọn ọmọ rẹ múlẹ̀ títí lae,n óo sì gbé ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”
5 Jẹ́ kí ojú ọ̀run máa kọrin ìyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ, OLÚWA;kí àwọn eniyan mímọ́ sì máa kọrin ìyìn òtítọ́ rẹ.
6 Nítorí ta ni a lè fi wé ọ ní ọ̀run, OLUWA?Ta ni ó dàbí OLUWA láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run?
7 Ọlọrun, ìwọ ni a bẹ̀rù ninu ìgbìmọ̀ àwọn eniyan mímọ́,o tóbi, o sì lẹ́rù ju gbogbo àwọn tí ó yí ọ ká lọ?
8 OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, ta ló lágbára bíi rẹ?OLUWA, òtítọ́ rẹ yí ọ ká.
9 Ò ń jọba lórí òkun tí ń ru;nígbà tí ìgbì rẹ̀ bá ru sókè, ìwọ ni ò ń mú kí ó rọlẹ̀.
10 Ìwọ ni o wó Rahabu mọ́lẹ̀ bí òkú ẹran;o fi ọwọ́ agbára rẹ fọ́n àwọn ọ̀tá rẹ ká.
11 Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé pẹlu;ìwọ ni o tẹ ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ dó.
12 Ìwọ ni o dá àríwá ati gúsù,òkè Tabori ati òkè Herimoni ń fi ayọ̀yin orúkọ rẹ.
13 Alágbára ni ọ́;agbára ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;o gbé ọwọ́ agbára rẹ sókè.
14 Òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ;ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ ń lọ ṣiwaju rẹ.
15 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó mọ ìhó ayọ̀ nnì,àwọn tí ń rìn ninu ìmọ́lẹ̀ ojurere rẹ, OLUWA,
16 àwọn tí ń yọ̀ nítorí orúkọ rẹ tọ̀sán-tòru,tí sì ń gbé òdodo rẹ lárugẹ.
17 Nítorí ìwọ ni ògo ati agbára wọn;nípa ojurere rẹ sì ni a ti ní ìṣẹ́gun.
18 Dájúdájú, OLUWA, tìrẹ ni ààbò wa;ìwọ, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ọba wa.
19 Ní ìgbàanì, o sọ ninu ìran fún olùfọkànsìn rẹ pé,“Mo ti fi adé dé alágbára kan lórí,mo ti gbé ẹnìkan ga tí a yàn láàrin àwọn eniyan.
20 Mo ti rí Dafidi, iranṣẹ mi;mo ti fi òróró mímọ́ mi yàn án;
21 kí ọwọ́ agbára mi lè máa gbé e ró títí lae,kí ọwọ́ mi sì máa fún un ní okun.
22 Ọ̀tá kan kò ní lè borí rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan burúkú kò ní tẹ orí rẹ̀ ba.
23 N óo run ọ̀tá rẹ̀ níwájú rẹ̀;n óo sì bá àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ kanlẹ̀.
24 Òtítọ́ mi ati ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ yóo wà pẹlu rẹ̀;orúkọ mi ni yóo sì máa fi ṣẹgun.
25 N óo mú ìjọba rẹ̀ gbòòrò dé òkun;agbára rẹ̀ yóo sì tàn dé odò Yufurate
26 Yóo ké pè mí pé, ‘Ìwọ ni Baba mi,Ọlọrun mi, ati Àpáta ìgbàlà mi.’
27 N óo fi ṣe àkọ́bí,àní, ọba tí ó tóbi ju gbogbo ọba ayé lọ.
28 N óo máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn án títí lae;majẹmu èmi pẹlu rẹ̀ yóo sì dúró ṣinṣin.
29 Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae;ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa bẹ níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ.
30 “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀,tí wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi,
31 bí wọ́n bá tàpá sí àṣẹ mi,tí wọn kò sì pa òfin mi mọ́;
32 n óo nà wọ́n lẹ́gba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,n óo sì nà wọ́n ní pàṣán nítorí àìdára wọn.
33 Ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kò ní kúrò lára rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yẹ òtítọ́ mi.
34 N kò ni yẹ majẹmu mi,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ pada.
35 “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti fi ìwà mímọ́ mi búra:n kò ní purọ́ fún Dafidi.
36 Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae,ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa wà níwájú mi, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń yọ.
37 A óo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí òṣùpá títí lae,yóo dúró ṣinṣin níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ.”
38 Ṣugbọn nisinsinyii inú rẹ ti ru sí ẹni àmì òróró rẹ;o ti ta á nù,o sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
39 O ti pa majẹmu tí o bá iranṣẹ rẹ dá tì,o ti ba adé rẹ̀ jẹ́, o ti fi wọ́lẹ̀.
40 O ti wó gbogbo odi rẹ̀;o sì ti sọ ilé ìṣọ́ rẹ̀ di ahoro.
41 Gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ ní ń kó o lẹ́rù;ó ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀.
42 O ti ran àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́;o ti mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ yọ̀ ọ́.
43 Àní, o ti ba gbogbo ohun ìjà rẹ̀ jẹ́,o kò sì ràn án lọ́wọ́ lójú ogun.
44 O ti gba ọ̀pá àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀;o sì ti wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀.
45 O ti gé ìgbà èwe rẹ̀ kúrú;o sì ti da ìtìjú bò ó.
46 Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA? Ṣé títí lae ni o óo máa fi ara pamọ́ fún mi?Yóo ti pẹ́ tó tí ibinu rẹ yóo máa jò bí iná?
47 OLUWA, ranti bí ọjọ́ ayé ẹ̀dá ti gùn mọ,ati pé ẹ̀dá lásán ni ọmọ eniyan!
48 Ta ló wà láyé tí kò ní kú?Ta ló lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ lọ́wọ́ agbára isà òkú?
49 OLUWA, níbo ni ìfẹ́ rẹ ìgbàanì tí kì í yẹ̀ wà,tí o búra fún Dafidi pẹlu òtítọ́ rẹ?
50 OLUWA, ranti bí èmi, iranṣẹ rẹ, ti di ẹni yẹ̀yẹ́;ati bí mo ti ń farada ẹ̀gàn àwọn eniyan,
51 OLUWA àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ẹni tí o fi àmì òróró yàn ṣe yẹ̀yẹ́,wọ́n sì ń kẹ́gàn ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀.