Orin Dafidi 9 BM

Ọpẹ́ fún Ọlọrun nítorí Ìdájọ́ Òdodo Rẹ̀

1 OLUWA, tọkàntọkàn ni n óo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ;n óo ròyìn gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ.

2 N óo yọ̀, inú mi yóo sì máa dùn nítorí rẹ;n óo kọ orin ìyìn orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.

3 Nígbà tí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà,wọ́n ṣubú, wọ́n sì parun níwájú rẹ.

4 Nítorí ìwọ ni o fi ìdí ẹ̀tọ́ mi múlẹ̀, tí o sì dá mi láre;ìwọ ni o jókòó lórí ìtẹ́, o sì ṣe ìdájọ́ òdodo.

5 O bá àwọn orílẹ̀-èdè wí,o pa àwọn eniyan burúkú run,o sì pa orúkọ wọn rẹ́ títí lae.

6 O pa àwọn ọ̀tá run patapata, o sọ ìlú wọn di ahoro,o sì sọ wọ́n di ẹni ìgbàgbé.

7 Ṣugbọn OLUWA gúnwà títí lae,ó ti fi ìdí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀ múlẹ̀.

8 Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé,yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.

9 OLUWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,òun ni ibi ìsádi ní ìgbà ìpọ́njú.

10 Àwọn tí ó mọ̀ ọ́ yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ;nítorí ìwọ, OLUWA, kìí kọ àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀.

11 Ẹ kọrin ìyìn sí OLUWA, tí ó gúnwà ní Sioni!Ẹ kéde iṣẹ́ rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè!

12 Nítorí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ranti,kò sì gbàgbé igbe ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.

13 OLUWA, ṣàánú fún mi!Wò ó bí àwọn ọ̀tá mi ṣe ń pọ́n mi lójú.Gbà mí kúrò létí bèbè ikú,

14 kí n lè kọrin ìyìn rẹ,kí n sì lè yọ ayọ̀ ìgbàlà rẹ lẹ́nu ibodè Sioni.

15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti jìn sinu kòtò tí wọ́n gbẹ́,wọ́n sì ti kó sinu àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀.

16 OLUWA ti fi ara rẹ̀ hàn, ó ti ṣe ìdájọ́,àwọn eniyan burúkú sì ti kó sinu tàkúté ara wọn.

17 Àwọn eniyan burúkú,àní, gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọrun, ni yóo lọ sinu isà òkú.

18 Nítorí pé OLUWA kò ní fi ìgbà gbogbo gbàgbé àwọn aláìní,bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn talaka kò ní já sí òfo títí lae.

19 Dìde, OLUWA, má jẹ́ kí eniyan ó borí,jẹ́ kí á ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè níwájú rẹ.

20 OLUWA, da ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ bò wọ́n,jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé aláìlágbára eniyan ni àwọn.