Orin Dafidi 69 BM

Igbe fún Ìrànlọ́wọ́

1 Gbà mí, Ọlọrun,nítorí omi ti mù mí dé ọrùn.

2 Mo ti rì sinu irà jíjìn,níbi tí kò ti sí ohun ìfẹsẹ̀tẹ̀;mo ti bọ́ sinu ibú,omi sì ti bò mí mọ́lẹ̀.

3 Mo sọkún títí àárẹ̀ mú mi,ọ̀nà ọ̀fun mi gbẹ,ojú mi sì di bàìbàì,níbi tí mo ti dúró, tí mò ń wo ojú ìwọ Ọlọrun mi.

4 Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí pọ̀,wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ.Àwọn tí ó fẹ́ pa mí run lágbára.Àwọn ọ̀tá mi ń parọ́ mọ́ mi,àwọn nǹkan tí n kò jíni wọ́n ní kí n fi dandan dá pada.

5 Ọlọrun, o mọ ìwà òmùgọ̀ mi,àwọn àṣìṣe mi kò sì fara pamọ́ fún ọ.

6 Má tìtorí tèmi dójúti àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ,OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,má sì tìtorí mi sọ àwọn tí ń wá ọ di ẹni àbùkù,Ọlọrun Israẹli.

7 Nítorí tìrẹ ni mo ṣe di ẹni ẹ̀gàn,tí ìtìjú sì bò mí.

8 Mo ti di àlejò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi,mo sì di àjèjì lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ìyá mi.

9 Nítorí pé ìtara ilé rẹ ni ó jẹ mí lógún,ìwọ̀sí àwọn tí ó ń pẹ̀gàn rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀.

10 Nígbà tí mo fi omijé gbààwẹ̀,ó di ẹ̀gàn fún mi.

11 Nígbà tí mò ń wọ aṣọ ọ̀fọ̀,mo di ẹni àmúpòwe.

12 Èmi ni àwọn tí ń jókòó lẹ́nu ibodèfi ń ṣe ọ̀rọ̀ sọ;àwọn ọ̀mùtí sì ń fi mí ṣe orin kọ.

13 Ṣugbọn ní tèmi, OLUWA, ìwọ ni mò ń gbadura síní àkókò tí ó bá yẹ, Ọlọrun,ninu ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,ninu agbára ìgbàlà rẹ, Ọlọrun dá mi lóhùn.

14 Yọ mí ninu irà yìí, má jẹ́ kí n rì,gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

15 Má jẹ́ kí ìgbì omi bò mí mọ́lẹ̀,kí ibú omi má gbé mi mì,kí isà òkú má sì padé mọ́ mi.

16 Dá mi lóhùn, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹtí kì í yẹ̀ dára;fojú rere wò mí, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ àánú rẹ.

17 Má ṣe fi ojú pamọ́ fún èmi, iranṣẹ rẹ,nítorí tí mo wà ninu ìdààmú,yára dá mi lóhùn.

18 Sún mọ́ mi, rà mí pada,kí o sì tú mi sílẹ̀ nítorí àwọn ọ̀tá mi!

19 O mọ ẹ̀gàn mi,o mọ ìtìjú ati àbùkù mi;o sì mọ gbogbo àwọn ọ̀tá mi.

20 Ẹ̀gàn ti mú kí inú mi bàjẹ́,tóbẹ́ẹ̀ tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sìmò ń retí àánú ṣugbọn kò sí;mò ń retí olùtùnú, ṣugbọn n kò rí ẹnìkan.

21 Iwọ ni wọ́n sọ di oúnjẹ fún mi,nígbà tí òùngbẹ sì ń gbẹ mí,ọtí kíkan ni wọ́n fún mi mu.

22 Jẹ́ kí tabili oúnjẹ tí wọ́n tẹ́ fún arawọn di ẹ̀bìtì fún wọn;kí àsè ẹbọ wọn sì di tàkúté.

23 Jẹ́ kí ojú wọn ṣú,kí wọn má lè ríran;kí gbogbo ara wọn sì máa gbọ̀n rìrì.

24 Rọ òjò ibinu rẹ lé wọn lórí,kí o sì jẹ́ kí wọ́n rí gbígbóná ibinu rẹ.

25 Kí ibùdó wọn ó di ahoro,kí ẹnikẹ́ni má sì gbé inú àgọ́ wọn.

26 Nítorí ẹni tí o ti kọlù ni wọ́n tún gbógun tì;ẹni tí o ti ṣá lọ́gbẹ́ ni wọ́n sì tún ń pọ́n lójú.

27 Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;má sì jẹ́ kí wọ́n rí ìdáláre lọ́dọ̀ rẹ.

28 Pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè;kí á má sì kọ orúkọ wọn mọ́ ti àwọn olódodo.

29 Ojú ń pọ́n mi, mo sì ń jẹ̀rora;Ọlọrun, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè!

30 Èmi ó fi orin yin orúkọ Ọlọrun;n óo fi ọpẹ́ gbé e ga.

31 Èyí yóo tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn ju akọ mààlúù lọ,àní, akọ mààlúù tòun tìwo ati pátákò rẹ̀.

32 Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo rí i,inú wọn yóo dùn;ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín sọjí.

33 Nítorí OLUWA a máa gbọ́ ti àwọn aláìní,kì í sìí kẹ́gàn àwọn eniyan rẹ̀ tí ó wà ní ìgbèkùn.

34 Jẹ́ kí ọ̀run ati ayé kí ó yìn ín,òkun ati gbogbo ohun tí ó ń rìn káàkiri ninu wọn.

35 Nítorí Ọlọrun yóo gba Sioni là;yóo sì tún àwọn ìlú Juda kọ́;àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo máa gbé inú rẹ̀,yóo sì di tiwọn.

36 Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo jogún rẹ̀;àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ̀ yóo sì máa gbé inú rẹ̀.