1 OLUWA tóbi, ó sì yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọní ìlú Ọlọrun wa.
2 Òkè mímọ́ rẹ̀, tí ó ga, tí ó sì lẹ́wà,ni ayọ̀ gbogbo ayé.Òkè Sioni, ní àríwá, lọ́nà jíjìn réré,ìlú ọba ńlá.
3 Ninu ilé ìṣọ́ ìlú náà, Ọlọrun ti fi ara rẹ̀ hàn bí ibi ìsádi.
4 Wò ó! Àwọn ọba kó ara wọn jọ;wọ́n jùmọ̀ gbógun tì í.
5 Nígbà tí wọ́n fojú kàn án, ẹnu yà wọ́n,ìpayà mú wọn, wọ́n sì sá;
6 ìwárìrì mú wọn níbẹ̀;ìrora sì bá wọn bí obinrin tí ń rọbí.
7 Ó fọ́ wọn bí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn tií fọ́ ọkọ̀ Taṣiṣi.
8 Bí a ti gbọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí,ní ìlú OLUWA àwọn ọmọ ogun,ní ìlú Ọlọrun wa:Ọlọrun fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae.
9 Ninu tẹmpili rẹ, Ọlọrun,à ń ṣe àṣàrò lórí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.
10 Ọlọrun, ìyìn rẹ tàn ká,bí orúkọ rẹ ṣe tàn dé òpin ayé,iṣẹ́ rere kún ọwọ́ rẹ.
11 Jẹ́ kí inú òkè Sioni kí ó dùn,kí gbogbo Juda sì máa yọ̀nítorí ìdájọ́ rẹ.
12 Ẹ rìn yí Sioni po; ẹ yí i ká;ẹ ka àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀;
13 ẹ ṣàkíyèsí odi rẹ̀;ẹ wọ inú gbogbo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lọ,kí ẹ lè ròyìn fún ìran tí ń bọ̀
14 pe: “Ọlọrun yìí ni Ọlọrun wa,lae ati laelae.Òun ni yóo máa ṣe amọ̀nà wa títí lae.”