1 OLUWA ni mo sá di;ẹ ṣe lè wí fún mi pé,“Fò lọ sórí òkè bí ẹyẹ;
2 ẹ wo àwọn eniyan burúkú bí wọ́n ti kẹ́ ọfà;wọ́n fa ọrun;wọ́n sì fi òkùnkùn bojú láti ta olódodo lọ́fà.
3 Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́,kí ni olódodo lè ṣe?”
4 OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀,ìtẹ́ rẹ̀ wà lọ́run;OLUWA ń kíyèsí àwọn ọmọ eniyan,ó sì ń yẹ̀ wọ́n wò.
5 OLUWA ń yẹ àwọn olódodo, ati eniyan burúkú wò,ṣugbọn tọkàntọkàn ni ó kórìíra àwọn tí ó fẹ́ràn ìwà ipá.
6 Yóo rọ̀jò ẹ̀yinná ati imí ọjọ́ gbígbóná sórí àwọn eniyan burúkú;ìjì gbígbóná ni yóo sì jẹ́ ìpín wọn.
7 Nítorí olódodo ni OLUWA, ó sì fẹ́ràn òdodo;àwọn olóòótọ́ ni yóo rí ojú rẹ̀.