Orin Dafidi 147 BM

Ọlọrun Alágbára

1 Ẹ yin OLUWA!Nítorí tí ó dára láti máa kọ orin ìyìn sí Ọlọrun wa;nítorí olóore ni, orin ìyìn sì yẹ ẹ́.

2 OLUWA ní ń kọ́ ìlú Jerusalẹmu;òun ni yóo kó àwọn ọmọ Israẹli tí a fọ́n ká jọ.

3 Ó ń tu àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́ ninu,ó sì ń dí ọgbẹ́ wọn.

4 Òun ló mọ iye àwọn ìràwọ̀,òun ló sì fún gbogbo wọn lórúkọ.

5 OLUWA wa tóbi, ó sì lágbára pupọòye rẹ̀ kò ní ìwọ̀n.

6 OLUWA ní ń gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ró,òun ni ó sì ń sọ àwọn eniyan burúkú di ilẹ̀ẹ́lẹ̀.

7 Ẹ kọ orin ọpẹ́ sí OLUWA,ẹ fi hapu kọ orin dídùn sí Ọlọrun wa.

8 Ẹni tí ó fi ìkùukùu bo ojú ọ̀run,ó pèsè òjò fún ilẹ̀,ó mú koríko hù lórí òkè.

9 Òun ni ó ń fún àwọn ẹranko ní oúnjẹ,tí ó sì ń bọ́ ọmọ ẹyẹ ìwò, tí ó ń ké.

10 Kì í ṣe agbára ẹṣin ni inú rẹ̀ dùn sí,kì í sì í ṣe inú agbára eniyan ni ayọ̀ rẹ̀ wà.

11 Ṣugbọn inú OLUWA dùn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,àwọn tí ó ní ìrètí ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

12 Gbé OLUWA ga, ìwọ Jerusalẹmu!Yin Ọlọrun rẹ, ìwọ Sioni!

13 Ó fún ẹnubodè rẹ ní agbára,ó sì bukun àwọn tí ń gbé inú rẹ.

14 Ó jẹ́ kí alaafia wà ní ààlà ilẹ̀ rẹ,ó sì fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ ọ lábọ̀ọ́yó.

15 Ó pàṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,àṣẹ rẹ̀ sì múlẹ̀ kíá.

16 Ó da òjò dídì bo ilẹ̀ bí ẹ̀gbọ̀n òwú,ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú.

17 Ó sọ yìnyín sílẹ̀ bí òkò,ta ni ó lè fara da òtútù rẹ̀?

18 Ó sọ̀rọ̀, wọ́n yọ́,ó fẹ́ afẹ́fẹ́, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn.

19 Ó ṣí ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá fún Jakọbu,ó sì fi òfin ati ìlànà rẹ̀ han Israẹli.

20 Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè kankan rí,wọn kò sì mọ ìlànà rẹ̀.Ẹ yin OLUWA!