1 Dẹtí sílẹ̀, ìwọ olùṣọ́-aguntan Israẹli,Ìwọ tí ò ń tọ́jú àwọn ọmọ Josẹfu bí agbo ẹran.Ìwọ tí o gúnwà láàrin àwọn kerubu, yọ bí ọjọ́
2 níwájú Efuraimu ati Bẹnjamini ati Manase.Sọ agbára rẹ jí,kí o sì wá gbà wá là.
3 Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun;fi ojurere wò wá,kí á le gbà wá là.
4 OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa bínú sí aduraàwọn eniyan rẹ?
5 O ti fi omijé bọ́ wọn bí oúnjẹ,o sì ti fún wọn ní omijé mu ní àmuyó.
6 O ti mú kí àwọn aládùúgbò wa máa jìjàdù lórí wa;àwọn ọ̀tá wa sì ń fi wá rẹ́rìn-ín láàrin ara wọn.
7 Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun;fi ojurere wò wá,kí á lè là.
8 O mú ìtàkùn àjàrà kan jáde láti Ijipti;o lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde, o sì gbìn ín.
9 O ro ilẹ̀ fún un;ó ta gbòǹgbò wọlẹ̀, igi rẹ̀ sì gbilẹ̀.
10 Òjìji rẹ̀ bo àwọn òkè mọ́lẹ̀,ẹ̀ka rẹ sì bo àwọn igi kedari ńláńlá;
11 àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tàn kálẹ̀ títí kan òkun,àwọn èèhù rẹ̀ sì kan odò ńlá.
12 Kí ló dé tí o fi wó ògiri ọgbà rẹ̀,tí gbogbo àwọn tí ń kọjá lọsì fi ń ká èso rẹ̀?
13 Àwọn ìmàdò inú ìgbẹ́ ń jẹ ẹ́ ní àjẹrun,gbogbo àwọn nǹkan tí ń káàkiri ninu oko sì ń jẹ ẹ́.
14 Jọ̀wọ́ tún yipada, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun!Bojúwolẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì wò ó;kí o sì tọ́jú ìtàkùn àjàrà yìí,
15 ohun ọ̀gbìn tí o fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbìn,àní, ọ̀dọ́ igi tí o fi ọwọ́ ara rẹ tọ́jú.
16 Àwọn ọ̀tá ti dáná sun ún, wọ́n ti gé e lulẹ̀;fi ojú burúkú wò wọ́n, kí wọ́n ṣègbé!
17 Ṣugbọn di ẹni tí o fúnra rẹ yàn mú,àní, ọmọ eniyan, tí o fúnra rẹ sọ di alágbára.
18 Ṣe bẹ́ẹ̀, a kò sì ní pada lẹ́yìn rẹ;dá wa sí, a ó sì máa sìn ọ́!
19 Mú wa bọ̀ sípò, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun!Fi ojurere wò wá, kí á lè là!