1 Ẹ kọ orin titun sí OLUWA,nítorí tí ó ti ṣe ohun ìyanu;agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati apá mímọ́ rẹ̀ ni ó fi ṣẹgun.
2 OLUWA ti sọ ìṣẹ́gun rẹ̀ di mímọ̀,ó ti fi ìdáláre rẹ̀ hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè.
3 Ó ranti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ̀sí àwọn ọmọ Israẹli;gbogbo ayé ti rí ìṣẹ́gun Ọlọrun wa.
4 Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA;ẹ bú sí orin ayọ̀, kí ẹ sì kọ orin ìyìn.
5 Ẹ fi hapu kọ orin ìyìn sí OLUWA,àní, hapu ati ohùn orin dídùn.
6 Ẹ fun fèrè ati ìwokí ẹ sì hó ìhó ayọ̀ níwájú OLUWA Ọba.
7 Kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀,kí ayé hó, ati àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
8 Omi òkun, ẹ pàtẹ́wọ́;kí ẹ̀yin òkè sì fi ayọ̀ kọrin pọ̀
9 níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé;yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.