Orin Dafidi 44 BM

Adura Ààbò

1 Ọlọrun, a ti fi etí wa gbọ́,àwọn baba wa sì ti sọ fún wa,nípa àwọn ohun tí o ṣe nígbà ayé wọn,àní, ní ayé àtijọ́:

2 Ìwọ ni o fi ọwọ́ ara rẹ lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fún wọn,tí o sì fi ẹsẹ̀ àwọn baba wa múlẹ̀;o fi ìyà jẹ àwọn orílẹ̀-èdè náà,o sì jẹ́ kí ó dára fún àwọn baba wa.

3 Nítorí pé kì í ṣe idà wọn ni wọ́n fi gba ilẹ̀ náà,kì í ṣe agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun;agbára rẹ ni; àní, agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ,ati ojurere rẹ;nítorí pé inú rẹ dùn sí wọn.

4 Ìwọ ni Ọba mi ati Ọlọrun mi;ìwọ ni o fi àṣẹ sí i pé kí Jakọbu ó ṣẹgun.

5 Nípa agbára rẹ ni a fi bi àwọn ọ̀tá wa sẹ́yìn,orúkọ rẹ ni a fi tẹ àwọn tí ó gbógun tì wá mọ́lẹ̀.

6 Nítorí pé kì í ṣe ọrun mi ni mo gbẹ́kẹ̀lé;idà mi kò sì le gbà mí.

7 Ṣugbọn ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,o sì dójú ti àwọn tí ó kórìíra wa.

8 Ìwọ Ọlọrun ni a fi ń yangàn nígbà gbogbo;a óo sì máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ títí lae.

9 Sibẹ, o ti ta wá nù o sì ti rẹ̀ wá sílẹ̀,o ò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́.

10 O ti mú kí á sá fún àwọn ọ̀tá wa lójú ogun;àwọn tí ó kórìíra wa sì fi ẹrù wa ṣe ìkógun.

11 O ti ṣe wá bí aguntan lọ́wọ́ alápatà,o sì ti fọ́n wa káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.

12 O ti ta àwọn eniyan rẹ lọ́pọ̀,o ò sì jẹ èrè kankan lórí wọn.

13 O ti sọ wá di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wa;a di ẹni ẹ̀sín ati ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ó yí wa ká.

14 O sọ wá di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,ati ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin gbogbo ayé.

15 Àbùkù mi wà lára mi tọ̀sán-tòru,ìtìjú sì ti bò mí.

16 Ọ̀rọ̀ àwọn apẹ̀gàn ati apeni-níjà ṣẹ mọ́ mi lára,lójú àwọn ọ̀tá mi ati àwọn tí ó fẹ́ gbẹ̀san.

17 Gbogbo nǹkan yìí ló ṣẹlẹ̀ sí wa,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbàgbé rẹ,bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹ majẹmu rẹ.

18 Ọkàn wa kò pada lẹ́yìn rẹ,bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹsẹ̀ kúrò ninu ìlànà rẹ,

19 sibẹ o fọ́ wa túútúú fún ìjẹ àwọn ẹranko,o sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

20 Bí ó bá jẹ́ pé a gbàgbé orúkọ Ọlọrun wa,tabi tí a bá bọ oriṣa,

21 ṣebí Ọlọrun ìbá ti mọ̀?Nítorí òun ni olùmọ̀ràn ọkàn.

22 Ṣugbọn nítorí tìrẹ ni wọ́n fi ń pa wá tọ̀sán-tòru,tí a kà wá sí aguntan lọ́wọ́ alápatà.

23 Para dà, OLUWA, kí ló dé tí o fi ń sùn?Jí gìrì! Má ta wá nù títí lae.

24 Kí ló dé tí o fi ń fi ojú pamọ́?Kí ló dé tí o fi gbàgbé ìpọ́njú ati ìnira wa?

25 Nítorí pé àwọn ọ̀tá ti tẹ̀ wá mọ́lẹ̀;àyà wa sì lẹ̀ mọ́lẹ̀ típẹ́típẹ́.

26 Gbéra nílẹ̀, kí o ràn wá lọ́wọ́!Gbà wá sílẹ̀ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.