1 Ẹ̀ṣẹ̀ ń gbin lọ́kàn eniyan burúkú,kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ninu èrò tirẹ̀.
2 Nítorí pé lọ́kàn rẹ̀ a máa pọ́n ara rẹ̀,pé kò sí ẹni tí ó lè rí ẹ̀ṣẹ̀ òun,ká tó wá sọ pé yóo dá òun lẹ́bi.
3 Ọ̀rọ̀ ìkà ati ẹ̀tàn ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.Ó ti dáwọ́ ire ṣíṣe dúró;kò sì hu ìwà ọlọ́gbọ́n mọ́.
4 A máa pète ìkà lórí ibùsùn rẹ̀;a máa rin ọ̀nà tí kò tọ́;kò sì kórìíra ibi.
5 OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga kan ọ̀run;òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.
6 Òtítọ́ rẹ dàbí òkè ńlá;ìdájọ́ rẹ sì jìn bí ibú omi.OLUWA, àtènìyàn, àtẹranko ni ò ń gbàlà.
7 Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ níye lórí pupọ, Ọlọrun!Àwọn ọmọ eniyan a máa sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ.
8 Wọ́n ń rí oúnjẹ jẹ ní àjẹyó ní ilé rẹ;nǹkan mímu tí ń ṣàn bí odò,ni o sì ń fún wọn mu.
9 Nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà;ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a ti ń rí ìmọ́lẹ̀.
10 Túbọ̀ máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀han àwọn tí ó mọ̀ ọ́,sì máa fi òdodo rẹ han àwọn ọlọ́kàn mímọ́.
11 Má jẹ́ kí àwọn agbéraga borí mi,má sì jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú lé mi kúrò.
12 Ẹ wo àwọn aṣebi níbi tí wọ́n ṣubú sí;wọ́n dà wólẹ̀, wọn kò sì le dìde.