1 Ẹ gbọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè!Ẹ dẹtí sílẹ̀, gbogbo aráyé,
2 ati mẹ̀kúnnù àtọlọ́lá,àtolówó ati talaka!
3 Ẹnu mi yóo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n;àṣàrò ọkàn mi yóo sì jẹ́ ti òye.
4 N óo tẹ́tí sílẹ̀ sí òwe;n óo sì fi hapu túmọ̀ rẹ̀.
5 Kí ló dé tí n óo fi bẹ̀rù ní àkókò ìyọnu,nígbà tí iṣẹ́ ibi àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi bá yí mi ká,
6 àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,tí wọ́n sì ń yangàn nítorí wọ́n ní ọrọ̀ pupọ?
7 Dájúdájú, kò sí ẹni tí ó le ra ara rẹ̀ pada,tabi tí ó lè san owó ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ fún Ọlọrun;
8 nítorí pé ẹ̀mí eniyan níye lórí pupọ.Kò sí iye tí eniyan ní tí ó le kájú rẹ̀,
9 tí eniyan lè máa fi wà láàyè títí lae,kí ó má fojú ba ikú.
10 Yóo rí i pé ikú a máa pa ọlọ́gbọ́n,òmùgọ̀ ati òpè a sì máa rọ̀run;wọn a sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.
11 Ibojì wọn ni ilé wọn títí lae,ibẹ̀ ni ibùgbé wọn títí ayérayé,wọn ìbáà tilẹ̀ ní ilẹ̀ ti ara wọn.
12 Eniyan kò lè máa gbé ninu ọlá rẹ̀ títí ayé,bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo kú.
13 Ìpín àwọn tí ó ní igbẹkẹle asán nìyí,òun sì ni èrè àwọn tí ọrọ̀ wọn tẹ́ lọ́rùn.
14 Ikú ni ìpín wọn bí àgùntàn lásánlàsàn,ikú ni yóo máa ṣe olùṣọ́ wọn;ibojì ni wọ́n sì ń lọ tààrà.Wọn yóo jẹrà, ìrísí wọn óo sì parẹ́,Àwọn olódodo yóo jọba lórí wọn ní òwúrọ̀,ibojì ni yóo sì máa jẹ́ ilé wọn.
15 Ṣugbọn Ọlọrun yóo ra ẹ̀mí mi pada lọ́wọ́ ikúnítorí pé yóo gbà mí.
16 Má ba ara jẹ́ bí ẹnìkan bá di olówó,tí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i.
17 Nítorí pé ní ọjọ́ tí ó bá kú,kò ní mú ohunkohun lọ́wọ́ lọ;dúkìá rẹ̀ kò sì ní bá a wọ ibojì.
18 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí ó wà láàyè,ó rò pé Ọlọrun bukun òun,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé a máa yin eniyannígbà tí nǹkan bá ń dára fún un,
19 yóo kú bí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti kú,kò sì ní fojú kan ìmọ́lẹ̀ mọ́.
20 Eniyan kò lè máa gbé inú ọlá rẹ̀ títí ayé;bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo ku.