1 N óo máa yìn ọ́ tọkàntọkàn OLUWA,lójú àwọn oriṣa ni n óo máa kọrin ìyìn sí ọ.
2 Ní ìtẹríba, n óo kọjú sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ,n óo sì máa yin orúkọ rẹ,nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ,nítorí pé o gbé ọ̀rọ̀ rẹ ati orúkọ rẹ ga ju ohunkohun lọ.
3 Ní ọjọ́ tí mo ké pè ọ́, o dá mi lóhùn,o sì fún mi ní agbára kún agbára.
4 OLUWA, gbogbo ọba ayé ni yóo máa yìn ọ́,nítorí pé wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.
5 Wọn óo sì máa kọrin nípa iṣẹ́ OLUWA,nítorí pé ògo OLUWA tóbi.
6 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ga lọ́lá,ó ka àwọn onírẹ̀lẹ̀ sí,ṣugbọn ó mọ àwọn onigbeeraga lókèèrè.
7 Bí mo tilẹ̀ wà ninu ìpọ́njú,sibẹ, o dá mi sí;o dojú ìjà kọ ibinu àwọn ọ̀tá mi,o sì fi ọwọ́ agbára rẹ gbà mí.
8 OLUWA yóo mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí mi,OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.Má kọ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sílẹ̀.