Orin Dafidi 107 BM

Yíyin OLUWA fún Oore Rẹ̀

1 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

2 Kí àwọn tí OLUWA ti rà pada kí ó wí bẹ́ẹ̀,àní, àwọn tí ó yọ kúrò ninu ìpọ́njú,

3 tí ó kó wọn jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀n-ọn-nì,láti ìhà ìlà oòrùn ati láti ìhà ìwọ̀ oòrùn,láti ìhà àríwá ati láti ìhà gúsù.

4 Àwọn kan ń káàkiri ninu aṣálẹ̀,wọn kò sì rí ọ̀nà dé ìlú tí wọ́n lè máa gbé.

5 Ebi pa wọ́n, òùngbẹ gbẹ wọ́n,ó sì rẹ̀ wọ́n wá láti inú.

6 Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì yọ wọ́n kúrò ninu ìṣẹ́ wọn.

7 Ó kó wọn gba ọ̀nà tààrà jáde,lọ sí ìlú tí wọ́n lè máa gbé.

8 Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún àwọn ọmọ eniyan.

9 Nítorí pé ó fi omi tẹ́ àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ lọ́rùn,ó sì fi oúnjẹ dáradára bọ́ àwọn tí ebi ń pa ní àbọ́yó.

10 Àwọn kan jókòó ninu òkùnkùn pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,wọ́n wà ninu ìgbèkùn ati ìpọ́njú, a sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n,

11 nítorí pé wọ́n tàpá sí òfin Ọlọrun,wọ́n sì pẹ̀gàn ìmọ̀ràn ọ̀gá ògo.

12 Làálàá mú kí agara dá ọkàn wọn,wọ́n ṣubú lulẹ̀ láìsí olùrànlọ́wọ́.

13 Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì gbà wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.

14 Ó yọ wọ́n kúrò ninu òkùnkùn ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,ó sì já ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn.

15 Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan.

16 Nítorí pé ó fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ,ó sì gé ọ̀pá ìdábùú irin ní àgéjá.

17 Àwọn kan ninu wọn di òmùgọ̀nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,ojú sì pọ́n wọn nítorí àìdára wọn.

18 Oúnjẹ rùn sí wọn,wọ́n sì súnmọ́ bèbè ikú.

19 Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.

20 Ó sọ̀rọ̀, ó sì mú wọn lára dá,ó tún kó wọn yọ ninu ìparun.

21 Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,àní, nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan.

22 Kí wọn máa rú ẹbọ ọpẹ́,kí wọn sì máa fi orin ayọ̀ ròyìn iṣẹ́ rẹ̀.

23 Àwọn kan wọ ọkọ̀ ojú omi,wọ́n ń ṣòwò lórí agbami òkun,

24 wọ́n rí ìṣe OLUWA,àní iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ninu ibú.

25 Ó pàṣẹ, ìjì líle sì bẹ̀rẹ̀ sí jà,tóbẹ́ẹ̀ tí ìgbì omi fi ru sókè.

26 Àwọn ọkọ̀ ojú omi fò sókè roro,wọ́n sì tún já wá sílẹ̀ dòò, sinu ibú,jìnnìjìnnì bò wọ́n ninu ewu tí wọ́n wà.

27 Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n káàkiri bí ọ̀mùtí,gbogbo ọgbọ́n sì parẹ́ mọ́ wọn ninu.

28 Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.

29 Ó mú kí ìgbì dáwọ́ dúró,ó sì mú kí ríru omi òkun rọlẹ̀ wọ̀ọ̀.

30 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nígbà tí ilẹ̀ rọ̀,ó sì mú kí wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté ìfẹ́ wọn.

31 Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan.

32 Kí wọn gbé e ga láàrin ìjọ eniyan,kí wọn sì yìn ín ní àwùjọ àwọn àgbà.

33 Ó sọ odò di aṣálẹ̀,ó sọ orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ,

34 ó sọ ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀ oníyọ̀,nítorí ìwà burúkú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

35 Ó sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,ó sì sọ ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi.

36 Ó jẹ́ kí àwọn tí ebi ń pa máa gbé ibẹ̀,wọ́n sì tẹ ìlú dó, láti máa gbé.

37 Wọ́n dáko, wọ́n gbin àjàrà,wọ́n sì kórè lọpọlọpọ.

38 Ó bukun wọn, ó mú kí wọn bí sí i lọpọlọpọ,kò sì jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọ́n dínkù.

39 Nígbà tí wọ́n dínkù, tí a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,nípa ìnira, ìpọ́njú, ati ìṣòro,

40 ó da ẹ̀gàn lu àwọn ìjòyè,ó sì mú kí wọn máa rìn kiri ní aṣálẹ̀,níbi tí kò sí ọ̀nà.

41 Ṣugbọn ó yọ aláìní kúrò ninu ìpọ́njú,ó sì mú kí ìdílé wọn pọ̀ sí i bí agbo ẹran.

42 Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn,a sì pa àwọn eniyan burúkú lẹ́nu mọ́.

43 Kí ẹni tí ó gbọ́n kíyèsí nǹkan wọnyi;kí ó sì fi òye gbé ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀.