1 Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA,ìwọ ni ààbò mi, má di etí sí mi.Nítorí bí o bá dákẹ́ sí min óo dàbí àwọn òkú, tí wọ́n ti lọ sinu kòtò.
2 Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi,bí mo ti ń kígbe sí ọ pé kí o ràn mí lọ́wọ́;tí mo gbé ọwọ́ mi sókèsí ìhà ilé mímọ́ rẹ.
3 Má ṣe kó mi lọ pẹlu àwọn eniyan burúkú,pẹlu àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,àwọn tí ń bá àwọn aládùúgbò wọnsọ ọ̀rọ̀ alaafia,ṣugbọn tí ètekéte ń bẹ ninu ọkàn wọn.
4 San án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn,àní gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ burúkú wọn;san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn,fún wọn ní èrè tí ó tọ́ sí wọn.
5 Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ OLUWA sí,wọn kò sì bìkítà fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,OLUWA yóo sọ wọ́n di ilẹ̀,kò sì ní gbé wọn dìde mọ́.
6 Ẹni ìyìn ni OLUWA!Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7 OLUWA ni agbára ati asà mi,òun ni mo gbẹ́kẹ̀lé;ó ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi sì kún fún ayọ̀;mo sì fi orin ìyìn dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
8 OLUWA ni agbára àwọn eniyan rẹ̀;òun ni ààbò ìgbàlà fún ẹni àmì òróró rẹ̀.
9 Gba àwọn eniyan rẹ là, OLUWA,kí o sì bukun ilẹ̀ ìní rẹ.Jẹ́ olùṣọ́-aguntan wọn,kí o sì máa tọ́jú wọn títí lae.