Orin Dafidi 92 BM

Orin Ìyìn

1 Ó dára kí eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA;kí ó sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá Ògo;

2 ó dára kí eniyan máa kéde ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ní òwúrọ̀,kí ó máa kéde òtítọ́ rẹ ní alẹ́,

3 pẹlu orin, lórí ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá,ati hapu.

4 Nítorí ìwọ, OLUWA, ti mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ rẹ;OLUWA, mò ń fi ayọ̀ kọrin nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

5 Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tóbi pupọ, OLÚWA!Èrò rẹ sì jinlẹ̀ pupọ!

6 Òpè eniyan kò lè mọ̀,kò sì le yé òmùgọ̀:

7 pé bí eniyan burúkú bá tilẹ̀ rú bíi koríko,tí gbogbo àwọn aṣebi sì ń gbilẹ̀,ó dájú pé ìparun ayérayé ni òpin wọn.

8 Ṣugbọn ẹni àgbéga títí lae ni ọ́, OLUWA.

9 Wò ó, OLUWA, àwọn ọ̀tá rẹ yóo parun;gbogbo àwọn aṣebi yóo sì fọ́n ká.

10 Ṣugbọn o ti gbé mi ga, o ti fún mi lágbára bíi ti ẹfọ̀n;o ti da òróró dáradára sí mi lórí.

11 Mo ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi,mo sì ti fi etí mi gbọ́ ìparun àwọn ẹni ibi tí ó gbé ìjà kò mí.

12 Àwọn olódodo yóo gbilẹ̀ bí igi ọ̀pẹ,wọn óo dàgbà bí igi kedari ti Lẹbanoni.

13 Wọ́n dàbí igi tí a gbìn sí ilé OLUWA,tí ó sì ń dàgbà ninu àgbàlá Ọlọrun wa.

14 Wọn á máa so èso títí di ọjọ́ ogbó wọn,wọn á máa lómi lára, ewé wọn á sì máa tutù nígbà gbogbo;

15 láti fihàn pé olóòótọ́ ni OLUWA;òun ni àpáta mi, kò sì sí aiṣododo lọ́wọ́ rẹ̀.