Orin Dafidi 50 BM

Ìsìn Tòótọ́

1 OLUWA, Ọlọrun Alágbára ti sọ̀rọ̀:ó ké sí gbogbo ayéláti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

2 Ọlọrun yọ bí ọjọ́ láti Sioni,ìlú tó dára, tó lẹ́wà.

3 Ọlọrun wa ń bọ̀, kò dákẹ́:iná ajónirun ń jó níwájú rẹ̀;ìjì líle sì ń jà yí i ká.

4 Ó ké sí ọ̀run lókè;ó pe ayé pẹlu láti gbọ́ ìdájọ́ tí yóo ṣe fún àwọn eniyan rẹ̀.

5 Ó ní, “Ẹ kó àwọn olùfọkànsìn mi jọ sọ́dọ̀ mi,àwọn tí wọ́n ti fi ẹbọ bá mi dá majẹmu!”

6 Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀ péỌlọrun ni onídàájọ́.

7 “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, n óo sọ̀rọ̀,Israẹli, n óo takò yín.Èmi ni Ọlọrun, Ọlọrun yín.

8 N kò ba yín wí nítorí ẹbọ rírú;nígbà gbogbo ni ẹ̀ ń rú ẹbọ sísun sí mi.

9 N kò ní gba akọ mààlúù lọ́wọ́ yín,tabi òbúkọ láti agbo ẹran yín.

10 Nítorí èmi ni mo ni gbogbo ẹran inú igbó,tèmi sì ni gbogbo mààlúù tó wà lórí ẹgbẹrun òkè.

11 Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ni mo mọ̀,tèmi sì ni gbogbo nǹkan tí ń rìn ninu pápá.

12 “Bí ebi bá tilẹ̀ pa mí, ẹ̀yin kọ́ ni n óo sọ fún,nítorí èmi ni mo ni gbogbo ayé ati àwọn nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.

13 Ṣé èmi a máa jẹ ẹran akọ mààlúù?Àbí mà máa mu ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́?

14 Ọpẹ́ ni kí ẹ fi rúbọ sí Ọlọrun,kí ẹ sì máa san ẹ̀jẹ́ yín fún Ọ̀gá Ògo.

15 Ẹ ké pè mí ní ọjọ́ ìṣòro;n óo gbà yín, ẹ óo sì yìn mí lógo.”

16 Ṣugbọn Ọlọrun bi àwọn eniyan burúkú pé,“Ẹ̀tọ́ wo ni ẹ níláti máa ka àwọn òfin mi,tabi láti máa mú ẹnu ba ìlànà mi?

17 Nítorí ẹ kórìíra ẹ̀kọ́;ẹ sì ti ta àṣẹ mi nù.

18 Tí ẹ bá rí olè, ẹ̀yin pẹlu rẹ̀ a dọ̀rẹ́;ẹ sì ń bá àwọn panṣaga kẹ́gbẹ́.

19 “Ọ̀rọ̀ ibi dùn lẹ́nu yín pupọ;ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sì yọ̀ létè yín.

20 Ẹ̀ ń jókòó sọ̀rọ̀ arakunrin yín níbi:ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ nípa ọmọ ìyá yín.

21 Gbogbo nǹkan wọnyi ni ẹ ti ṣe tí mo sì dákẹ́;ẹ wá ń rò ninu yín pé, èmi yín rí bákan náà.Ṣugbọn nisinsinyii mò ń ba yín wí,mo sì ń fi ẹ̀sùn kàn yín.

22 “Nítorí náà, ẹ fi èyí lékàn, ẹ̀yin tí ẹ gbàgbé Ọlọrun,kí n má baà fà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kò sì ní sí ẹni tí yóo gbà yín kalẹ̀.

23 Ẹni tí ó bá mu ọpẹ́ wá, tí ó fi rúbọ sí mi, ni ó bu ọlá fún mi;ẹni tí ó bá sì rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni èmi Ọlọrun yóo gbà là.”