Orin Dafidi 108 BM

Adura Ìrànlọ́wọ́ láti Borí Ọ̀tá

1 Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrunọkàn mi dúró ṣinṣin.N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́.Jí, ìwọ ọkàn mi!

2 Ẹ jí ẹ̀yin ohun èlò ìkọrin ati hapu!Èmi fúnra mi náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu,

3 OLUWA, n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwọn eniyan,n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

4 Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ,òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.

5 Kí á gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, Ọlọrun,kí ògo rẹ sì kárí gbogbo ayé.

6 Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là,fi ọwọ́ agbára rẹ gbà wá, kí o sì dá mi lóhùn.

7 Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀,ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu,n óo sì pín àfonífojì Sukotu.

8 Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase.Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi,Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.

9 Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé,n óo sì hó ìhó ìṣẹ́gun lórí Filistia.”

10 Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà?Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu?

11 Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀?Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa lọ sójú ogun mọ́.

12 Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa,nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan.

13 Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọ́run, a óo ṣe akin;nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.