1 OLUWA, má fi ibinu bá mi wí!Má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà!
2 Nítorí pé ọfà rẹ ti wọ̀ mí lára,ọwọ́ rẹ sì ti bà mí.
3 Kò sí ibìkan tí ó gbádùn ní gbogbo ara minítorí ibinu rẹ;kò sì sí alaafia ninu gbogbo egungun mi,nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi.
4 Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti bò mí lórí mọ́lẹ̀;ó rìn mí mọ́lẹ̀ bí ẹrù ńlátí ó wúwo jù fún mi.
5 Ọgbẹ́ mi ń kẹ̀, ó sì ń rùn,nítorí ìwà òmùgọ̀ mi,
6 Ìbànújẹ́ dorí mi kodò patapata,mo sì ń ṣọ̀fọ̀ kiri tọ̀sán-tòru.
7 Gbogbo ẹ̀gbẹ́ mi ń gbóná fòò,kò sí ibìkan tí ó gbádùn lára mi.
8 Àárẹ̀ mú mi patapata, gbogbo ara sì wó mi;mò ń kérora nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi.
9 OLUWA, gbogbo ìfẹ́ ọkàn mi ni o mọ̀,ìmí ẹ̀dùn mi kò sì pamọ́ fún ọ.
10 Àyà mi ń lù pì pì pì, ó rẹ̀ mí láti inú wá;ojú mi sì ti di bàìbàì.
11 Àwọn ọ̀rẹ́ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi takété sí mi nítorí àrùn mi,àwọn ẹbí mi sì dúró lókèèrè réré.
12 Àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí mi dẹ tàkúté sílẹ̀ dè mí,àwọn tí ń wá ìpalára mi ń sọ̀rọ̀ ìparun mi,wọ́n sì ń pète àrékérekè tọ̀sán-tòru.
13 Ṣugbọn mo ṣe bí adití, n kò gbọ́,mo dàbí odi tí kò le sọ̀rọ̀.
14 Àní, mo dàbí ẹni tí kò gbọ́rọ̀,tí kò sì ní àwíjàre kan lẹ́nu.
15 Ṣugbọn, OLUWA, ìwọ ni mò ń dúró dè;OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni o óo dá mi lóhùn.
16 Nítorí tí mò ń gbadura pé,kí àwọn tí ń pẹ̀gàn mi má yọ̀ mínígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yẹ̀.
17 Nítorí pé mo ti fẹ́rẹ̀ ṣubú,mo sì wà ninu ìrora nígbà gbogbo.
18 Mo jẹ́wọ́ àṣìṣe mi,mo sì káàánú fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.
19 Àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí lágbára,àwọn tí ó kórìíra mi láìtọ́ sì pọ̀.
20 Àwọn tí ń fi ibi san oore fún mi ní ń gbógun tì mí,nítorí pé rere ni mò ń ṣe.
21 OLUWA, má kọ̀ mí sílẹ̀,Ọlọrun mi, má jìnnà sí mi.
22 Yára wá ràn mí lọ́wọ́, OLUWA, ìgbàlà mi.