1 Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi.Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé,
2 “Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi,sibẹ, wọn kò borí mi.”
3 Wọ́n to ẹgba sí mi lẹ́yìn,gbogbo ẹ̀yìn mi lé bíi poro oko.
4 Ṣugbọn olódodo ni OLUWA,ó ti gé okùn àwọn eniyan burúkú.
5 Ojú yóo ti gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni,a óo lé wọn pada sẹ́yìn.
6 Wọn óo dàbí koríko tí ó hù lórí òrùlé,tí kì í dàgbà kí ó tó gbẹ.
7 Kò lè kún ọwọ́ ẹni tí ń pa koríko;kò sì lè kún ọwọ́ ẹni tí ń di koríko ní ìtí.
8 Àwọn èrò ọ̀nà kò sì ní kí ẹni tí ń gé e pé:“OLUWA óo fèrè síṣẹ́ o!Ẹ kúuṣẹ́, OLUWA óo fèrè sí i.”