Orin Dafidi 37 BM

Ìgbẹ̀yìn Àwọn Eniyan Burúkú

1 Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí àwọn eniyan burúkú;má sì jowú àwọn aṣebi;

2 nítorí pé kíákíá ni wọn yóo gbẹ bí i koríko;wọn óo sì rọ bí ewé.

3 Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; kí o sì máa ṣe rere.Máa gbe ilẹ̀ náà; ewu kò sì ní wu ọ́.

4 Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA;yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́.

5 Fi ọ̀nà rẹ lé OLUWA lọ́wọ́;gbẹ́kẹ̀lé e, yóo sì ṣe ohun tí ó yẹ.

6 Yóo mú kí ìdáláre rẹ tàn bí ìmọ́lẹ̀;ẹ̀tọ́ rẹ yóo sì hàn kedere bí ọ̀sán gangan.

7 Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA; fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé e.Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí ẹni tí nǹkan ń dára fún;tabi nítorí ẹni tí ń gbèrò ibi, tí ó sì ń ṣe é.

8 Yẹra fún ibinu; sì yàgò fún ìrúnú.Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná; ibi ni àyọrísí rẹ̀.

9 Nítorí pé a óo pa àwọn eniyan burúkú run;ṣugbọn àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWAni yóo jogún ilẹ̀ náà.

10 Ẹ fún eniyan burúkú ní ìgbà díẹ̀ sí i, yóo pòórá;ẹ̀ báà wá a títí ní ààyè rẹ̀, kò ní sí níbẹ̀.

11 Ṣugbọn àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóo jogún ilẹ̀ náà:wọn óo máa gbádùn ara wọn;wọn óo sì ní alaafia lọpọlọpọ.

12 Eniyan burúkú dìtẹ̀ mọ́ olódodo;ó sì ń wò ó bíi kíkú bíi yíyè.

13 Ṣugbọn OLUWA ń fi eniyan burúkú rẹ́rìn-ín,nítorí ó mọ̀ pé ọjọ́ ìparun rẹ̀ ń bọ̀.

14 Àwọn eniyan burúkú fa idà yọ, wọ́n sì kẹ́ ọfà wọnláti gba ẹ̀mí talaka ati aláìní,láti pa àwọn tí ń rìn lọ́nà ẹ̀tọ́.

15 Ṣugbọn idà wọn ni o óo fi pa wọ́n,ọrun wọn yóo sì dá.

16 Nǹkan díẹ̀ tí olódodo nídára ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú.

17 Nítorí OLUWA yóo ṣẹ́ apá eniyan burúkú,ṣugbọn yóo gbé olódodo ró.

18 OLUWA a máa tọ́jú àwọn aláìlẹ́bi;ilẹ̀ ìní wọn yóo jẹ́ tiwọn títí lae.

19 Ojú kò ní tì wọ́n nígbà tí àjálù bá dé;bí ìyàn tilẹ̀ mú, wọn óo jẹ, wọn óo yó.

20 Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé;àwọn ọ̀tá OLUWA yóo pòórá bí ẹwà ewékowọn óo parẹ́ bí èéfín tí í parẹ́.

21 Bí eniyan burúkú bá yá owó, kò ní san;ṣugbọn ẹni rere ní ojú àánú, ó sì lawọ́.

22 Nítorí pé àwọn tí Ọlọrun bá bukun ni yóo jogún ilẹ̀ náà,ṣugbọn àwọn tí ó bá fi gégùn-ún yóo parun.

23 OLUWA níí darí ìgbésẹ̀ ẹni;a sì máa fi ẹsẹ̀ ẹni tí inú rẹ̀ bá dùn sí múlẹ̀.

24 Bí ó tilẹ̀ ṣubú, kò ní lulẹ̀ lógèdèǹgbé,nítorí OLUWA yóo gbé e ró.

25 Mo ti jẹ́ ọmọde rí; mo sì ti dàgbà:n kò tíì ri kí á kọ olódodo sílẹ̀,tabi kí ọmọ rẹ̀ máa tọrọ jẹ.

26 Olódodo ní ojú àánú, a sì máa yáni ní nǹkan,ayọ̀ ń bẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀.

27 Ẹ yẹra fún ibi; ẹ sì máa ṣe rere;kí ẹ lè wà ní ààyè yín títí lae.

28 Nítorí OLUWA fẹ́ràn ẹ̀tọ́;kò ní kọ àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sílẹ̀.Yóo máa ṣọ́ wọn títí lae,ṣugbọn a óo pa àwọn ọmọ eniyan burúkú run.

29 Àwọn ẹni rere ni yóo jogún ilẹ̀ náà;wọn óo sì máa gbé orí rẹ̀ títí lae.

30 Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa jáde lẹ́nu ẹni rere,a sì máa sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́.

31 Òfin Ọlọrun rẹ̀ wà ní ọkàn rẹ̀;ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í yà kúrò níbẹ̀.

32 Eniyan burúkú ń ṣọ́ olódodo,ó ń wá ọ̀nà ati pa á.

33 OLUWA kò ní fi olódodo lé e lọ́wọ́,tabi kí ó jẹ́ kí á dá olódodo lẹ́bi ní ilé ẹjọ́.

34 Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, sì máa tọ ọ̀nà rẹ̀,yóo gbé ọ ga, kí o lè jogún ilẹ̀ náà;nígbà tí a bá pa àwọn eniyan burúkú run, o óo fojú rẹ rí i.

35 Mo ti rí eniyan burúkú tí ń halẹ̀ mọ́ni,tí ó ga bí igi kedari ti Lẹbanoni.

36 Ṣugbọn nígbà tí mo tún gba ibẹ̀ kọjá,mo wò ó, kò sí níbẹ̀ mọ́;mo wá a, ṣugbọn n kò rí i.

37 Ṣe akiyesi ẹni pípé;sì wo olódodo dáradára,nítorí pé ìgbẹ̀yìn ẹni tí ń wá alaafia yóo dára.

38 Ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo parun patapata,a óo sì run ọmọ àwọn eniyan burúkú.

39 Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìgbàlà àwọn olódodo ti ń wá;òun ni alátìlẹ́yìn wọn ní àkókò ìṣòro.

40 OLUWA a máa ràn wọ́n lọ́wọ́, a sì máa gbà wọ́n;a máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú,a sì máa gbà wọ́n là,nítorí pé òun ni wọ́n sá di.