Orin Dafidi 135 BM

Orin Ìyìn

1 Ẹ yin OLUWA.Ẹ yin orúkọ OLUWA;ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀,

2 ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jọ́sìn ninu ilé OLUWA,tí ẹ wà ní àgbàlá ilé Ọlọrun wa.

3 Ẹ yin OLUWA, nítorí pé ó ṣeun;ẹ kọrin ìyìn sí i,nítorí pé olóore ọ̀fẹ́ ni.

4 Nítorí pé OLUWA ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀,ó ti yan Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀.

5 Èmi mọ̀ pé OLUWA tóbi,ati pé ó ju gbogbo oriṣa lọ.

6 Bí ó ti wu OLUWA ni ó ń ṣelọ́run ati láyé,ninu òkun ati ninu ibú.

7 Òun ló gbá ìkùukùu jọ láti òpin ilẹ̀ ayé,ó fi mànàmáná fún òjò,ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀.

8 Òun ló pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti,ati teniyan ati tẹran ọ̀sìn.

9 Ẹni tí ó rán iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu sí ilẹ̀ Ijipti,ó rán sí Farao ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀.

10 Ẹni tí ó pa orílẹ̀-èdè pupọ run;ó pa àwọn ọba alágbára:

11 Sihoni ọba àwọn Amori,Ogu ọba Baṣani,ati gbogbo ọba ilẹ̀ Kenaani.

12 Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀;ó pín in fún Israẹli bí ohun ìní wọn.

13 OLUWA, orúkọ rẹ yóo wà títí lae,òkìkí rẹ óo sì máa kàn títí ayé.

14 OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre,yóo sì ṣàánú àwọn iranṣẹ rẹ̀.

15 Wúrà ati fadaka ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù fi ṣe oriṣa wọn,iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n.

16 Wọ́n lẹ́nu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀,wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò lè ríran.

17 Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò lè gbọ́ràn,bẹ́ẹ̀ ni kò sí èémí kan ní ẹnu wọn.

18 Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóo dàbí wọn,ati gbogbo àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé wọn.

19 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ yin OLUWA,ẹ̀yin ará ilé Aaroni, ẹ yin OLUWA!

20 Ẹ̀yin ará ilé Lefi, ẹ yin OLUWA,ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ yìn ín!

21 Ẹ yin OLUWA ní Sioni,ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu!Ẹ yin OLUWA!